عن عثمان رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«خَيْرُكُمْ مَنْ تَعَلَّمَ الْقُرْآنَ وَعَلَّمَهُ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 5027]
المزيــد ...
Lati ọdọ Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn”.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5027]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa pe ẹni ti o ni ọlá ju ninu awọn Mùsùlùmí ti o si tun ga ju ni ipo ni ọdọ Ọlọhun ni: Ẹni ti o ba kọ́ Kuraani, ni kika ati hiha, ati kike e ni pẹlẹpẹlẹ, ati agbọye rẹ, ati itumọ rẹ, ti o tun wa kọ́ ẹlòmíràn ni ohun ti n bẹ lọdọ rẹ ninu imọ Kuraani pẹlu lílò ó.