+ -

عَنْ أَبِي وَاقِدٍ اللَّيْثِيِّ رضي الله عنه:
أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لَمَّا خَرَجَ إِلَى حُنَيْنٍ مَرَّ بِشَجَرَةٍ لِلْمُشْرِكِينَ يُقَالُ لَهَا: ذَاتُ أَنْوَاطٍ يُعَلِّقُونَ عَلَيْهَا أَسْلِحَتَهُمْ، فَقَالُوا: يَا رَسُولَ اللهِ، اجْعَلْ لَنَا ذَاتَ أَنْوَاطٍ كَمَا لَهُمْ ذَاتُ أَنْوَاطٍ، فَقَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «سُبْحَانَ اللهِ! هَذَا كَمَا قَالَ قَوْمُ مُوسَى {اجْعَلْ لَنَا إِلَهًا كَمَا لَهُمْ آلِهَةٌ} [الأعراف: 138] وَالَّذِي نَفْسِي بِيَدِهِ لَتَرْكَبُنَّ سُنَّةَ مَنْ كَانَ قَبْلَكُمْ».

[صحيح] - [رواه الترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 2180]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Waaqid Al-Laythiy - ki Ọlọhun yọnu si i:
Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigba ti o jade lọ si Hunayn o rekọja nibi igi kan ti o jẹ ti awọn ọṣẹbọ ti wọn n pe e ni: Dhaatu anwaat ti wọn maa n fi awọn nkan ija wọn kọ ọ, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ṣe dhaatu anwaat fun wa gẹgẹ bi wọn ṣe ni dhaatu anwaat, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Mimọ fun Ọlọhun! Eleyii da gẹgẹ bi nkan ti awọn ijọ Musa sọ {ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan} [Al-'A‘roof: 138] mo wa fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹ o maa tẹle ilana awọn ti wọn ṣaaju yin».

[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2180]

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade lọ sí Hunayn oun ni: Aaye kan ti o wa laarin Tọọif ati Makkah, ti awọn saabe kan si wa pẹlu rẹ awọn ti wọn ṣẹṣẹ wọ inu Isilaamu, Ni wọn ba rekọja nibi igi kan ti wọn n pe e ni: “Dhaatu anwaat”, iyẹn ni pe: èyí tí o ni awọn asokọ, awọn ọṣẹbọ maa n gbe e tobi ti wọn si maa n so awọn nkan ija wọn kọ ọ ati awọn nkan miran lati fi wa alubarika, Ni wọn ba tọrọ lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ki o ṣe igi kan bii rẹ fun wọn, ti wọn o maa so awọn nkan ija wọn kọ, lati fi wa alubarika; lẹni ti wọn n lero pe alamọri yii lẹtọọ, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe afọmọ ní ti kikọ gbolohun naa, ati ní ti gbigbe titobi fun Ọlọhun, ti o si sọ pe dajudaju gbolohun yii jọ gbolohun awọn ijọ Musa fun un: {ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan}, Nigba ti wọn ri awọn ti wọn n jọsin fun oriṣa ni wọn wa tọrọ pe ki awọn naa ni awọn oriṣa gẹgẹ bi awọn ọṣẹbọ naa ṣe ni awọn oriṣa, ati pe eleyii ni itẹle ilana wọn, Lẹyin naa ni o wa funni niroo - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe dajudaju ijọ yii a maa tẹle ilana awọn Juu ati Kristẹni, ti a si maa ṣe iṣe wọn, lẹni ti o fi n kilọ kuro nibi ìyẹn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọmọniyan le ri nkankan si daadaa ti yio lero pe yio sun un mọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, to si jẹ wipe yio gbe e jina si I ni.
  2. O tọ fun musulumi ki o ṣe afọmọ ki o si gbe titobi fun Ọlọhun nigba ti o ba gbọ nkan ti ko lẹtọọ ki wọn o maa sọ nipa ẹsin, ati nigba ti o ba n ṣe eemọ.
  3. Ninu ẹbọ ni wiwa alubarika pẹlu awọn igi ati awọn okuta ati nkan ti o yatọ si i, ati pe alubarika ọdọ Ọlọhun ni a ti maa n beere fun un.
  4. Okunfa jijọsin fun awọn oriṣa ni gbigbe wọn tobi, ati ṣiṣe atipo ni ọdọ wọn, ati wiwa alubarika pẹlu wọn.
  5. Jijẹ dandan titi awọn ilẹkun ati awọn ọna ti o le gbe wa de ibi ẹbọ.
  6. Nkan ti o wa ninu awọn ọrọ nipa bibu awọn Yahudi ati Nasaara ikilọ ni fun wa.
  7. Kikọ kuro nibi imaa farajọ awọn ara igba aimọ ati awọn Juu ati Nasaara, ayaafi nkan ti ẹri ba wa fun un pe ninu ẹsin wa lo wa.