عَنِ ابْنِ عَبَّاسٍ رضي الله عنهما:
أَنَّ رَجُلًا أَتَى النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَكَلَّمَهُ فِي بَعْضِ الْأَمْرِ، فَقَالَ: مَا شَاءَ اللهُ وَشِئْتَ، فَقَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أَجَعَلْتَنِي لِلَّهِ عَدْلًا؟ قُلْ: مَا شَاءَ اللهُ وَحْدَهُ».
[إسناده حسن] - [رواه ابن ماجه والنسائي في الكبرى وأحمد] - [السنن الكبرى للنسائي: 10759]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibn Abbas, ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji:
Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe bakannaa pẹlu Ọlọ́run ni? Sọ pé: Ohunkóhun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá fẹ́”.
[Isnaadu rẹ daa] - [Ibnu Maajah ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ahmad] - [As-Sunanul Kubrọ ti An-Nasaaiy - 10759]
Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi, o si ba a sọro nipa ọrọ ara rẹ, lẹ́yìn naa o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ ati ohunkohun ti o ba fẹ”, Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, bá tako ọrọ yii o si sọ fun un pe sise idapọ fifẹ ẹda pẹ̀lú fifẹ Ọlohun pẹlu lẹ́tà “waw” jẹ ìsẹbọ kekere si Ọlọhun, ko si lẹtọọ fun Musulumi lati sọ ọ, Lẹ́yìn náà, ó ṣamọ̀nà rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà pé: “Ohunkóhun tí Ọlọ́hun nìkan ṣoṣo ba fẹ́,” nítorí náà ó maa ya Ọlọ́hun sọ́tọ̀ nínú ìfẹ́ Rẹ̀, kò sì nii so fifẹ ẹni kankan mọ ọn pẹlu èyíkéyìí ninu iran asopọ.