+ -

عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المُؤمنينَ رضي الله عنها قَالَتْ:
دَخَلَ عَلَيَّ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، وَقَدْ سَتَرْتُ سَهْوَةً لِي بِقِرَامٍ فِيهِ تَمَاثِيلُ، فَلَمَّا رَآهُ هَتَكَهُ وَتَلَوَّنَ وَجْهُهُ وَقَالَ: «يَا عَائِشَةُ، أَشَدُّ النَّاسِ عَذَابًا عِنْدَ اللهِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ الَّذِينَ يُضَاهُونَ بِخَلْقِ اللهِ» قَالَتْ عَائِشَةُ: «فَقَطَعْنَاهُ فَجَعَلْنَا مِنْهُ وِسَادَةً أَوْ وِسَادَتَيْنِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2107]
المزيــد ...

Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti mi, mo si ti bo apoti iko-nnkan-si ti o jẹ temi pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan n bẹ nibẹ, nigba ti o wa ri i, o fa a ya ti oju rẹ si pọn, o wa sọ pe: "Irẹ 'Aaisha, Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun" 'Aaisha sọ pe: "A si ge e, a si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2107]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- ninu ile rẹ, lo ba ri ti wọn ti bo apoti iko nnkan si kekere ti wọn gbe ẹru sinu rẹ pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan abẹmi n bẹ nibẹ, awọ oju rẹ si yipada ni ti ibinu nitori Ọlọhun, o si fa a ya, o wa sọ pe: Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun pẹlu awọn aworan wọn. 'Aaisha sọ pe: A si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kikọ ibajẹ ni asiko riri rẹ ati aima lọra nibi ìyẹn, nigba ti ko ba si aburu nla ti o ju ìyẹn lọ nibẹ.
  2. Iya ni ọjọ igbedide maa yatọ nibamu si titobi ẹṣẹ.
  3. Yiya aworan awọn abẹmi wa ninu awọn ẹṣẹ ti wọn tobi julọ.
  4. Ninu ọgbọ́n ti o n bẹ nibi ṣíṣe leewọ yiya aworan ni afijọ ẹda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- boya oluyaworan gbero afijọ tabi ko gbero rẹ.
  5. Ojúkòkòrò sharia lori sisọ awọn dukia pẹlu ṣíṣe anfaani latara rẹ lẹyin gbigbe e jina si nnkan ti wọn ṣe leewọ nibẹ.
  6. Kikọ kuro nibi ṣíṣe awọn aworan abẹmi lori èyíkéyìí ìrísí ti o le jẹ, koda ki o jẹ ìyílẹ̀.