+ -

عن خَوْلَةَ بِنْتَ حَكِيمٍ السُّلَمِيَّةَ قَالتْ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«مَنْ نَزَلَ مَنْزِلًا ثُمَّ قَالَ: أَعُوذُ بِكَلِمَاتِ اللهِ التَّامَّاتِ مِنْ شَرِّ مَا خَلَقَ، لَمْ يَضُرَّهُ شَيْءٌ حَتَّى يَرْتَحِلَ مِنْ مَنْزِلِهِ ذَلِكَ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2708]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Khaolat ọmọbìnrin Hakiim As-Sulamiyyah, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Ẹni ti o ba sọkalẹ si ààyè kan, ti o wa sọ pé: AUUZU BIKALIMAATIL LAAHIT-TAMMAATI MIN SHARRI MAA KHỌLAK, nǹkan kan ko nii ni in lara titi ti yoo fi kuro ni aaye rẹ yẹn”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2708]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ ìjọ rẹ sọ́nà lọ sibi ìdìrọ̀mọ́ ati ìsádi ti o maa ṣe àǹfààní ti gbogbo nnkan ti a n ṣọ́ra fun ti èèyàn n bẹ̀rù maa lọ pẹ̀lú rẹ nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ si ààyè kan lórí ilẹ̀, boya o wa ni ìrìn-àjò ni, tabi ìjáde ìgbafẹ́, tabi ohun ti o yatọ si ìyẹn: Pẹ̀lú pe ki o dìrọ̀ mọ́ ki o si sádi àwọn gbólóhùn Ọlọhun ti o pe nibi ọla rẹ ati ibukun rẹ ati àǹfààní rẹ, eyi ti o la kuro nibi gbogbo àléébù, níbi aburu gbogbo ẹ̀dá ti o ni aburu lára, ọkàn rẹ maa wa balẹ ni ààyè yẹn nibi gbogbo nnkan ti o ba le ṣe e ni suta lópin ìgbà tí o ba ṣi wa nibẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Wiwa iṣọra ìjọsìn ni, oun naa ni eyi ti o ba jẹ pẹlu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, tabi awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ.
  2. Ìní-ẹ̀tọ́ wiwa iṣọra pẹlu ọrọ Ọlọhun; torí pé o jẹ ọkan ninu awọn ìròyìn Rẹ, yatọ si ìwá-ìṣọ́ra pẹlu èyíkéyìí ẹ̀dá, ẹbọ ni ìyẹn.
  3. Ọla ti n bẹ fun adua yii ati alubarika rẹ.
  4. Wiwa ààbò pẹ̀lú àwọn iranti Ọlọhun jẹ okùnfà láti ṣọ́ ẹrú kúrò nibi aburú.
  5. Bíba ìwá-ìṣọ́ra pẹ̀lú ohun ti o yatọ si Ọlọhun jẹ́, bii alujannu, ati awọn opidan, ati awọn ẹni èké, ati awọn mìíràn.
  6. Adua yii jẹ nnkan ti o ba sharia mu fun ẹni tí ó ba sọ̀kalẹ̀ si ààyè kan ni ilé tabi ni ìrìn-àjò.