+ -

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الْخُدْرِيِّ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لَتَتَّبِعُنَّ سَنَنَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ، شِبْرًا بِشِبْرٍ، وَذِرَاعًا بِذِرَاعٍ، حَتَّى لَوْ دَخَلُوا فِي جُحْرِ ضَبٍّ لَاتَّبَعْتُمُوهُمْ» قُلْنَا: يَا رَسُولَ اللهِ آلْيَهُودَ وَالنَّصَارَى؟ قَالَ: «فَمَنْ؟».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2669]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Dajudaju ẹ ma maa tẹle oju ọna awọn ti wọn ṣáájú yin, ni odiwọn ìbú atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa, koda ki wọn wọnu isa agilinti ẹ maa tẹle wọn" a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, awọn Juu ati Nasara àbí? O sọ pe: "Taa waa tún ni?".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2669]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n fun wa ni iro nipa nnkan ti isesi awọn kan ninu ìjọ rẹ maa wa lori rẹ lẹyin ti o ba lọ tan, oun ni itẹle oju ọna Juu ati Nasara nibi awọn adisọkan wọn ati awọn iṣe wọn ati awọn àṣà wọn ni itẹle kan ti o péye ti o lágbára ni odiwọn ibu atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa, koda ki wọn wọnu isa agilinti awọn wọnyii maa wọle lẹyin wọn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ami kan ninu awọn ami ijẹ anabi rẹ nigba ti o sọ fun wa nipa ìyẹn ṣíwájú ki o to ṣẹlẹ̀ ti o si ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi o ṣe sọ.
  2. Kikọ kuro nibi ki Mùsùlùmí máa fara wé awọn alaigbagbọ, boya nibi awọn adisọkan wọn ni tabi ìjọsìn wọn, tabi awọn ọdun wọn tabi awọn aṣọ wọn ti a mọ̀ mọ̀ wọn.
  3. Alaye awọn nnkan ti a ko le ni imọlara rẹ pẹlu awọn apejuwe ti a le ni imọlara rẹ wa ninu awọn ọna ikọnilẹkọọ ninu Isilaamu.
  4. Agilinti ni: Ẹranko kan ti isa rẹ ṣókùnkùn gan-an ti oorun rẹ buru jàì, o wa nínú awọn ẹranko afayafa, o pọ ni awọn aṣálẹ̀, ìdí ti wọn fi dárúkọ ihò agilinti ni: “Bí o ṣe há gan-an àti pé kò dára, síbẹ̀, nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé oripa wọn, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ọ̀nà wọn, bí wọ́n bá wọ irú ibi tó há gan-an tó sì jẹ́ ibi tí kò dára bẹ́ẹ̀, wọ́n á gbà pẹ̀lú wọn! Ọlọhun sì ni Ẹni tí a ń bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.