+ -

عن ابنِ عُمَرَ رضي الله عنهما قال: قال رسولُ الله صلَّى الله عليه وسلم:
«مَن تَشَبَّهَ بِقَوْمٍ فَهُوَ مِنْهُمْ».

[حسن] - [رواه أبو داود وأحمد] - [سنن أبي داود: 4031]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”

[O daa] - [Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 4031]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni ti o ba fara wé àwọn èèyàn kan ninu awọn keferi, tabi awọn arúfin, tabi awọn ẹni rere- pẹ̀lú pe ki o ṣe nǹkan kan ninu awọn ìròyìn ti a mọ̀ wọn mọ̀ nibi adisọkan, tabi awọn ijọsin tabi awọn àṣà - ọkan ninu wọn ni; tori pé àfarawé wọn lóde máa ń yọrí sí àfarawé wọn ní inú, kò sì sí àní-àní pé àfarawé àwọn èèyàn máa ń jẹyọ latara ìjọlójú ni. Ó sì lè jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa gbé wọn tobi, kí wọ́n sì tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn, èyí sì lè mú kí èèyàn máa fara wé wọn titi dori inú ti o pamọ àti ìjọsìn – ki Ọlọhun ṣọ wa kúrò nibẹ-.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ikilọ kuro nibi ifarawe àwọn keferi ati awọn obilẹjẹ.
  2. Ṣiṣenilojukokoro lori fifi ara we àwọn ẹni rere ati ikọṣe wọn.
  3. Ìṣe àfarawé ni gbangba maa n jẹ ki èèyàn nífẹ̀ẹ́ dé inú.
  4. Ọmọniyan maa tọ́ si àdéhùn ìyà ati ẹṣẹ bi o ba ṣe ṣe àfarawé tó ati irú ìran àfarawé ti o ba ṣe.
  5. Kikọ afarawe awọn alaigbagbọ ninu ẹsin wọn ati ninu awọn aṣa wọn ti o jẹ ti wọn nìkan ni, ṣùgbọ́n nibi ohun ti ko ba ri bẹẹ, gẹgẹ bii kikọ iṣẹ ṣíṣe àwọn nǹkan ati iru bẹẹ, ko si ninu eewọ naa.