عن ابْنِ عُمَرَ رضي الله عنهما أنه سَمِعَ رَجُلًا يَقُولُ: لَا وَالْكَعْبَةِ، فَقَالَ ابْنُ عُمَرَ: لَا يُحْلَفُ بِغَيْرِ اللَّهِ، فَإِنِّي سَمِعْتُ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«مَنْ حَلَفَ بِغَيْرِ اللهِ فَقَدْ كَفَرَ أَوْ أَشْرَكَ».
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 1535]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní oun gbọ lẹnu ọkunrin kan ti n sọ pe: Rara o, oun fi Kaabah búra, ọmọ umar wa sọ fun un pe: A kò gbọdọ̀ fi nnkan tó yatọ si Ọlọhun Allah búra, tori dajudaju emi gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pe:
"Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ."
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 1535]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo pé ẹnikẹni tí ó bá fi nkan miran búra yatọ si Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, onitọhun ti ṣaigbagbọ si Ọlọhun, tabi ka ní ó ti ṣẹbọ pẹlu Rẹ̀; nítorí pé ìbúra ní í ṣe pẹ̀lú ìgbétítóbi fún nkan tí a fi búra, títóbi sì jẹ́ ti Ọlọ́hun Allah nìkan ṣoṣo; nitori naa, a kò gbọdọ̀ bura pẹlu nkankan ayafi Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, Mimọ ni fun Un, Ati pé ìbúra yii wà ninu ẹbọ kekere; ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó búra bá fi gbé títóbi fun nkan tó fi bura gẹgẹ bii ìgbétítóbi fún Ọlọ́hun Allah tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ; nigba naa, ó ti wà ninu ẹbọ nla niyẹn.