+ -

عَنْ عُمَرَ بْنِ الْخَطَّابِ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِنَّ اللهَ عَزَّ وَجَلَّ يَنْهَاكُمْ أَنْ تَحْلِفُوا بِآبَائِكُمْ»، قَالَ عُمَرُ: فَوَاللهِ مَا حَلَفْتُ بِهَا مُنْذُ سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ نَهَى عَنْهَا ذَاكِرًا وَلَا آثِرًا.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1646]
المزيــد ...

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- kọ fun yin lati maa bura pẹlu awọn baba yin", Umar sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mi ko bura pẹlu rẹ lati igba ti mo ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibẹ ni ti ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni tí ó gbé ìbúra ẹlòmíràn pẹ̀lú rẹ wa.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1646]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- kọ kuro nibi bibura pẹlu awọn baba, ẹni ti o ba fẹ búra, ko gbọdọ bura afi pẹlu Ọlọhun, ko si gbọdọ bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si i. Lẹyin naa, Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun ko bura pẹlu rẹ lati igba ti o ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibi ìyẹn, ni ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni ti o n gbé ọrọ ẹni ti o yàtọ̀ si i wa ti o bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe ibura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun leewọ, o dárúkọ awọn baba ni pato, nitori pe o wa ninu awọn àṣà asiko aimọkan.
  2. Al-halfu: Oun ni ibura pẹlu Ọlọhun tabi awọn orukọ Ọlọhun tabi awọn iroyin Ọlọhun lori àlámọ̀rí kan ninu awọn àlámọ̀rí lati kanpa mọ ọn.
  3. Ọla ti o n bẹ fun Umar- ki Ọlọhun yọnu si i- pẹlu yiyara itẹle àṣẹ rẹ, ati didaa agbọye rẹ ati ini àṣàjẹ rẹ.