عن أبي بكرة رضي الله عنه قال: قال النبي صلى الله عليه وسلم:
«أَلَا أُنَبِّئُكُمْ بِأَكْبَرِ الْكَبَائِرِ؟» ثَلَاثًا، قَالُوا: بَلَى يَا رَسُولَ اللهِ، قَالَ: «الْإِشْرَاكُ بِاللهِ، وَعُقُوقُ الْوَالِدَيْنِ» وَجَلَسَ وَكَانَ مُتَّكِئًا، فَقَالَ: «أَلَا وَقَوْلُ الزُّورِ»، قَالَ: فَمَا زَالَ يُكَرِّرُهَا حَتَّى قُلْنَا: لَيْتَهُ سَكَتَ.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2654]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Bakra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
“Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?” O sọ bẹẹ ni igba mẹ́ta, wọn sọ pe: A fẹ bẹẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: “Mimu orogun pẹ̀lú Ọlọhun ati yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji”, o wa jokoo, o si jẹ ẹni ti o rọgbọku tẹlẹ, ni o wa sọ pe: “Ẹ gbọ o, ati ọrọ eke”, o sọ pe: Ko wa yẹ ni ẹni ti n wi i ni awitunwi titi ti a fi sọ pe: Iba tiẹ si dakẹ.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2654]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - n sọ fun awọn saabe rẹ nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ nla, nitori naa o darukọ àwọn mẹta yii:
1. Imu orogun pọ mọ Ọlọhun: Oun naa ni fifi iran kan ninu awọn iran ijọsin fun ẹlòmíràn yatọ si Ọlọhun, ati fifi ẹni ti o yatọ si Ọlọhun dọgba pẹlu Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati ijẹ Oluwa Rẹ, ati awọn orukọ ati awọn iroyin Rẹ.
2. Yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji: Oun naa ni gbogbo ipalara ṣiṣe si obi mejeeji, yala ninu ọrọ tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn jù silẹ.
3. Ọrọ eke, ninu rẹ naa ni ẹri eke: Oun naa ni gbogbo ọrọ irọ ti wọn n fẹ lati fi tabuku ẹni ti o ba ṣẹlẹ si i, pẹlu gbígba dúkìá rẹ, tabi titayọ aala lori ọmọluabi rẹ tabi nkan ti o jọ bẹẹ.
Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti paara ikilọ kuro nibi ọrọ eke, lati ṣe itaniji lori ibajẹ rẹ (aidara rẹ) ati oripa aburu rẹ lori awujọ, titi ti awọn saabe fi sọ pe: Ko ba tiẹ si dakẹ; ni ti ìkáàánú rẹ, ati ikorira ohun ti o n yọ ọ lẹnu.