عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المُؤْمِنِينَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا أَنَّهَا قَالَتْ:
يَا رَسُولَ اللَّهِ، نَرَى الجِهَادَ أَفْضَلَ العَمَلِ، أَفَلاَ نُجَاهِدُ؟ قَالَ: «لَا، لَكُنَّ أَفْضَلُ الجِهَادِ: حَجٌّ مَبْرُورٌ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 1520]
المزيــد ...
Lati ọdọ Āisha iya àwọn mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)».
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1520]
Awọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - maa n ri ijagun si oju-ọna Ọlọhun ati biba awọn ọta ja ni iṣẹ ti o fi n lọla julọ, Ni Āisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ṣe awọn naa o nii jagun ni?
Ni o wa juwe wọn - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lọ sí ibi jihad ti o lọla julọ fun wọn, oun naa ni hajj atẹwọgba (ti o mọ kanga) eleyii ti o ṣe deedee tira Ọlọhun ati sunnah Anabi, ti o si tun la kuro nibi ẹṣẹ ati ṣekarimi.