عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: سمعت النبي صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ حَجَّ لِلهِ فَلَمْ يَرْفُثْ وَلَمْ يَفْسُقْ رَجَعَ كَيَوْمِ وَلَدَتْهُ أُمُّهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1521]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ti n sọ pe:
"Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i."
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1521]
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye pé ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kò sì bá obinrin lopọ, itumọ ibalopọ ni ibasun ati awọn ohun ti o ṣiwaju rẹ̀ gẹgẹ bii ifẹnukonu ati ifarakanra, wọn si maa n túmọ̀ rẹ̀ si ọrọ buruku, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, nípa dídá ẹ̀ṣẹ̀ àti ṣíṣe aburú. Ninu rírú ofin Ọlọhun ni ṣiṣe awọn èèwọ̀ gbígbé harami, yoo pada sile lati Hajji rẹ̀ ní ẹniti Ọlọhun ti darijin, gẹgẹ bi wọn ti n bi ọmọde lai ni ẹṣẹ kankan lọrun.