عَنِ ابْنِ عَبَّاسٍ رضي الله عنهما قَالَ:
قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِامْرَأَةٍ مِنَ الْأَنْصَارِ سَمَّاهَا ابْنُ عَبَّاسٍ فَنَسِيتُ اسْمَهَا: «مَا مَنَعَكِ أَنْ تَحُجِّي مَعَنَا؟» قَالَتْ: لَمْ يَكُنْ لَنَا إِلَّا نَاضِحَانِ فَحَجَّ أَبُو وَلَدِهَا وَابْنُهَا عَلَى نَاضِحٍ وَتَرَكَ لَنَا نَاضِحًا نَنْضِحُ عَلَيْهِ، قَالَ: «فَإِذَا جَاءَ رَمَضَانُ فَاعْتَمِرِي، فَإِنَّ عُمْرَةً فِيهِ تَعْدِلُ حَجَّةً».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1256]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ fun arabinrin kan ninu awọn Ansaar, Ibnu Abbās darukọ rẹ, mo wa gbagbe orukọ rẹ, o sọ fun un pe: «Kini o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa?» O sọ pe: A ko ni ju rakunmi meji lọ (ti a fi maa n fun oko wa lomi) ti ọkọ rẹ ati ọmọ rẹ si ṣe irinajo hajj lori ẹyọkan, o si fi ẹyọkan silẹ fun wa lati maa lo o lati fi maa pọn omi, o sọ pe: «Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1256]
Nígbà tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹri lati hajj idagbere, o sọ fún arabinrin kan ninu Ansaar ti ko ṣe hajj pe: Kini nkan ti o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa?
O wa mu awijare wa pe awọn ni rakunmi meji, ti ọkọ oun ati ọmọ òun si ṣe hajj lori ọkan ninu mejeeji, ti o si fi ẹyọkan silẹ lati lẹ maa fi i pọn omi lati inu kanga.
Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fun un ni iro pe dajudaju ṣiṣe umurah ninu oṣu ramadan ẹsan rẹ ṣe deedee ẹsan hajj.