+ -

عن أبي موسى الأشعري رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ حَمَلَ عَلَيْنَا السِّلَاحَ فَلَيْسَ مِنَّا».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 7071]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
«Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 7071]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n kilọ fun ẹni ti o ba da oju ija kọ awọn Musulumi pẹlu nnkan ìjà, lati le dẹru ba wọn ati lati fi tipa gba nkan wọn, nitori naa ẹni ti o ba ṣe ìyẹn lai lẹtọọ, o ti da ọran nla ati ẹṣẹ nla kan ninu awọn iya ẹṣẹ, ti o si lẹtọọ si adehun iya ti o le.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ikilọ ti o le kuro nibi ki Musulumi o ba awọn ọmọ-iya rẹ Musulumi ja.
  2. Ninu awọn ibajẹ ti o tobi julọ ni orilẹ ni yiyọ nkan ija si awọn Musulumi, ati ṣiṣe ibajẹ pẹlu ipaniyan.
  3. Adehun iya ti wọn sọ yẹn ko ko ìjà pẹlu ẹtọ sinu, gẹgẹ bii biba awọn olutayọ ala ati awọn aṣebajẹ ati awọn ti o yatọ si wọn ja.
  4. Ṣiṣe idẹruba awọn Musulumi pẹlu nkan ija tabi eyi ti o yatọ si i ni eewọ– koda ki o jẹ ni ọna awada -.