+ -

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الْخُدْرِيِّ قَالَ: خَرَجَ مُعَاوِيَةُ عَلَى حَلْقَةٍ فِي الْمَسْجِدِ، فَقَالَ: مَا أَجْلَسَكُمْ؟ قَالُوا: جَلَسْنَا نَذْكُرُ اللهَ، قَالَ آللَّهِ مَا أَجْلَسَكُمْ إِلَّا ذَاكَ؟ قَالُوا: وَاللهِ مَا أَجْلَسَنَا إِلَّا ذَاكَ، قَالَ: أَمَا إِنِّي لَمْ أَسْتَحْلِفْكُمْ تُهْمَةً لَكُمْ، وَمَا كَانَ أَحَدٌ بِمَنْزِلَتِي مِنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَقَلَّ عَنْهُ حَدِيثًا مِنِّي:
وَإِنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ خَرَجَ عَلَى حَلْقَةٍ مِنْ أَصْحَابِهِ، فَقَالَ: «مَا أَجْلَسَكُمْ؟» قَالُوا: جَلَسْنَا نَذْكُرُ اللهَ وَنَحْمَدُهُ عَلَى مَا هَدَانَا لِلْإِسْلَامِ، وَمَنَّ بِهِ عَلَيْنَا، قَالَ: «آللَّهِ مَا أَجْلَسَكُمْ إِلَّا ذَاكَ؟» قَالُوا: وَاللهِ مَا أَجْلَسَنَا إِلَّا ذَاكَ، قَالَ: «أَمَا إِنِّي لَمْ أَسْتَحْلِفْكُمْ تُهْمَةً لَكُمْ، وَلَكِنَّهُ أَتَانِي جِبْرِيلُ فَأَخْبَرَنِي أَنَّ اللهَ عَزَّ وَجَلَّ يُبَاهِي بِكُمُ الْمَلَائِكَةَ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2701]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Sa’ēd Al-Khuduriy o sọ pe: Mu’āwiya lọ sibi àpéjọ kan ninu masalasi, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo fun iranti Ọlọhun, o sọ pe: Ẹ bura pẹlu Ọlọhun pe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn? Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe: Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ko si si ẹnikankan ti o wa ni iru ipo mi si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti ẹgbawa hadiisi rẹ lati ọdọ rẹ (Anabi) kere to temi:
Ati pe dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade si ibi akojọ awọn saabe rẹ, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo lati maa ranti Ọlọhun ati lati maa fi ẹyin fun Un lori bi O ṣe fi wa m'ọna si Isilaamu, ati idẹkun ti O fi i ṣe le wa lori, o sọ pe: «Ẹ bura pẹlu Ọlọhun ṣe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn?» Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe : «Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika».

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2701]

Àlàyé

Mu‘āwiyah ọmọ Abu Sufyaan- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- jade sibi akojọ kan ninu masalasi, ni o wa bi wọn pe kini nkan ti wọn tori rẹ kojọ, Wọn wa sọ pe: A n ranti Ọlọhun ni, Ni o wa sọ - ki Ọlọhun yọnu si i - pe ki wọn o fi Ọlọhun bura pe wọn o gbero nkankan nibi ijokoo wọn ati akojọpọ wọn yẹn ayaafi iranti Ọlọhun, Wọn si bura fun un, Lẹyin naa ni o wa sọ fun wọn pe: Dajudaju kii ṣe pe mo ni ki ẹ bura láti fi ẹsun kan yin ati lati ṣe iyemeji nipa ododo yin, lẹyin naa ni o sọ nipa ipo rẹ si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pe ko si ẹnikankan ti ipo rẹ sunmọ ọn - Anabi - to oun; latari pe Umu Habiibah ọmọ ìyá rẹ obinrin jẹ iyawo Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe o tun wa ninu awọn ti wọn maa n kọ waayi (imisi), tòun ti bẹ́ẹ̀ náà ẹgbawa rẹ fun hadiisi kere, Ni o wa sọ fun wọn pe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade lati inu ile rẹ ni ọjọ kan, ni o wa ri wọn ti wọn jokoo ninu masalasi ti wọn n ṣe iranti Ọlọhun ti wọn si n yin In lori ọna Isilaamu ti O fi mọ wọn, ti O si fi ṣe idẹkun le wọn lori, ni o wa bi wọn leere - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o si tun ni ki wọn o bura bi iru nkan ti Mu‘āwiya - ki Ọlọhun yọnu si i - ṣe pẹlu awọn eeyan rẹ, Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun wọn idi ibeere rẹ fun ibura wọn: Oun ni pe Jubril - ki ọla Ọlọhun maa ba a - wa ba oun ti o si fun oun ni iro pe Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n fi yin ṣe iyanran niwaju awọn malaika, ti O si n ṣe afihan ọla yin fun wọn, ti O si tun n fi didaa iṣẹ yin han wọn, ti O si tun n yin yin loju wọn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla Mu‘āwiya - ki Ọlọhun yọnu si i - ati ojukokoro rẹ lori kikọṣe ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nibi mímú imọ de etiigbọ awọn eeyan.
  2. Jijẹ ẹtọ bibeere fun ibura lai si ifura si, lati ṣe itaniji lórí pataki ìròyìn naa.
  3. Ọla ti n bẹ fun awọn ijokoo iranti ati imọ ati pe dajudaju Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si i O si tun maa n ṣe iyanran pẹlu rẹ niwaju awọn malaika.