عَن عَبْدِ الرَّحْمَنِ بْنِ أَبِي لَيْلَى أَنَّهُمْ كَانُوا عِنْدَ حُذَيْفَةَ، فَاسْتَسْقَى فَسَقَاهُ مَجُوسِيٌّ، فَلَمَّا وَضَعَ القَدَحَ فِي يَدِهِ رَمَاهُ بِهِ، وَقَالَ: لَوْلاَ أَنِّي نَهَيْتُهُ غَيْرَ مَرَّةٍ وَلاَ مَرَّتَيْنِ -كَأَنَّهُ يَقُولُ: لَمْ أَفْعَلْ هَذَا-، وَلَكِنِّي سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«لاَ تَلْبَسُوا الحَرِيرَ وَلاَ الدِّيبَاجَ، وَلاَ تَشْرَبُوا فِي آنِيَةِ الذَّهَبِ وَالفِضَّةِ، وَلاَ تَأْكُلُوا فِي صِحَافِهَا، فَإِنَّهَا لَهُمْ فِي الدُّنْيَا وَلَنَا فِي الآخِرَةِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5426]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdur Rahmān ọmọ Abu Laylā o ni pe awọn wa ni ọdọ Hudhayfah, ni o ba beere fun omi, ni abọná kan ba fun un ni omi, nígbà tí o wa gbe ife omi yẹn fun un, o lẹ ẹ pada mọ ọn, o wa sọ pe: Ti kii ba ṣe pe mo ti kọ ọ fun un ni nkan ti kii ṣe ẹẹkan ti kii ṣe ẹẹmeji - bi ẹni ti n sọ pe: Mio ba ti ṣe nǹkan ti mo ṣe yii -, ṣugbọn mo gbọ ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe:
Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5426]
Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ fun awọn ọkunrin kuro nibi wíwọ asọ alaari pẹlu gbogbo iran rẹ. O si kọ fun awọn obinrin ati ọkunrin kuro nibi jijẹ ati mimu ninu awọn igba ati abọ wura ati fadaka. O si sọ pe ẹsa lo jẹ fun awọn mumini ni ọjọ igbedide; nítorí pé wọn jina si i ni aye lati tẹle aṣẹ Ọlọhun, Amọ awọn keferi ko nii jẹ ti wọn ni ọjọ ikẹyin; nitori pe wọn ti kanju lo awọn nkan igbadun wọn ni ile-aye pẹlu lilo ti wọn lo o, ati ìyapa aṣẹ Ọlọhun wọn.