عَنْ أَبِي مُوسَى رضي الله عنه قَالَ:
سُئِلَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَنِ الرَّجُلِ يُقَاتِلُ شَجَاعَةً، وَيُقَاتِلُ حَمِيَّةً، وَيُقَاتِلُ رِيَاءً، أَيُّ ذَلِكَ فِي سَبِيلِ اللهِ؟ فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «مَنْ قَاتَلَ لِتَكُونَ كَلِمَةُ اللهِ هِيَ الْعُلْيَا، فَهُوَ فِي سَبِيلِ اللهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1904]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere nipa arakunrin ti n jagun ni ti ijẹ akin, ati eyi ti n jagun ni ti ìgbónára, ati eyi ti n jagun ni ti karimi, ewo ninu rẹ ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun? Ni ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Ẹni ti o ba jagun lati jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke, oun ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1904]
Wọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere nipa ìyapa erongba awọn jagunjagun: Ẹni ti n jagun ni ti ijẹ akin, ati ẹni ti n jagun ni ti igbonara ati ẹni ti n jagun lati mọ ipo rẹ l'ọdọ awọn eeyan, ewo ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun ninu wọn? Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe dajudaju ẹni ti n jagun si oju-ọna Ọlọhun ni: Ẹni ti n jagun lati jẹ ki o jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke.