عَنْ عَبْدِ اللهِ بنِ مَسْعُودٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«أَوَّلُ مَا يُقْضَى بَيْنَ النَّاسِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِي الدِّمَاءِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1678]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan ni ọjọ igbedide ni nibi awọn ẹjẹ".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1678]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan nibi abosi apa kan si apakan ni ọjọ igbedide ni: Nibi awọn ẹjẹ, gẹgẹ bii pipa ènìyàn ati awọn ọgbẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi àlámọ̀rí awọn ẹjẹ, nitori pe ìbẹ̀rẹ̀ maa n jẹ pẹlu eyi ti o ṣe pataki julọ.
  2. Awọn ẹṣẹ maa tobi ni ibamu si titobi ibajẹ ti o wa nibẹ, ati ita awọn ẹmi alaiṣẹ silẹ wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu ibajẹ, ko si eyi ti o tobi ju u lọ afi ṣíṣe aigbagbọ ati dida orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (55)