+ -

عَنْ أَسْمَاءَ بِنْتِ أَبِي بَكْرٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا، قَالَتْ: قَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِنِّي عَلَى الحَوْضِ حَتَّى أَنْظُرَ مَنْ يَرِدُ عَلَيَّ مِنْكُمْ، وَسَيُؤْخَذُ نَاسٌ دُونِي، فَأَقُولُ: يَا رَبِّ مِنِّي وَمِنْ أُمَّتِي، فَيُقَالُ: هَلْ شَعَرْتَ مَا عَمِلُوا بَعْدَكَ، وَاللَّهِ مَا بَرِحُوا يَرْجِعُونَ عَلَى أَعْقَابِهِمْ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6593]
المزيــد ...

Lati ọdọ Asma ọmọ Abubakr, ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji, o sọ pe: Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé:
“Maa wa nibi adágún naa ki n le ri ẹni tí o maa wa si ọdọ mi ninu yin, wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ mi, mo maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara ìjọ mi ni wọn, wọn maa wa sọ pé: Ǹjẹ́ o mọ nǹkan ti wọn ṣe lẹ́yìn rẹ, mo fi Ọlọhun bura, wọn kò yẹ̀ wọn kò gbò ti wọn n kúrò nínú Isilaamu”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6593]

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe oun yoo wa nibi odò adágún rẹ ni ọjọ igbende láti ri awọn ti wọn maa wa síbẹ̀ nínú ìjọ rẹ, Wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ rẹ, ki ikẹ ati ọla maa ba a, o maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara mi ni wọn, ara ìjọ mi si ni wọn, Wọn maa sọ pé: Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọn ṣe lẹ́yìn ti ẹ ti jọ pínyà, mo fi Ọlọhun bura, wọ́n kò yẹ̀ wọn kò gbò ti wọn n kúrò nínú ẹsin wọn, wọn kì í ṣe ara rẹ, wọn o si ki i ṣe ara ìjọ rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Aanu Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, si awọn ijọ rẹ ati itaraṣaṣa rẹ si wọn.
  2. Ewu ìyapa ohun ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lórí rẹ.
  3. Igbaniyanju lati di sunna Anabi mu, ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a.