+ -

عَنْ أَبِي ذَرٍّ رضي الله عنه قَالَ:
قُلْتُ: يَا رَسُولَ اللهِ مَا آنِيَةُ الْحَوْضِ؟ قَالَ: «وَالَّذِي نَفْسُ مُحَمَّدٍ بِيَدِهِ لَآنِيَتُهُ أَكْثَرُ مِنْ عَدَدِ نُجُومِ السَّمَاءِ وَكَوَاكِبِهَا، أَلَا فِي اللَّيْلَةِ الْمُظْلِمَةِ الْمُصْحِيَةِ، آنِيَةُ الْجَنَّةِ مَنْ شَرِبَ مِنْهَا لَمْ يَظْمَأْ آخِرَ مَا عَلَيْهِ، يَشْخَبُ فِيهِ مِيزَابَانِ مِنَ الْجَنَّةِ، مَنْ شَرِبَ مِنْهُ لَمْ يَظْمَأْ، عَرْضُهُ مِثْلُ طُولِهِ، مَا بَيْنَ عَمَّانَ إِلَى أَيْلَةَ، مَاؤُهُ أَشَدُّ بَيَاضًا مِنَ اللَّبَنِ، وَأَحْلَى مِنَ الْعَسَلِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2300]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:
Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni àwọn ife ìmumi odo adágún naa? O sọ pe: “Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ ni alẹ́ ti o ṣókùnkùn ti ko ni ẹsujo, àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí o ba fi wọn mu omi, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ láéláé, omi n dà sínú rẹ lati inú gọ́tà méjì nínú alujanna, ẹni tí ó bá mu nínú rẹ̀, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ, ibu rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ, gígùn rẹ ni odiwọn ohun ti n bẹ láàrin ìlú Hammaan si ìlú Aelah, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, o si dùn ju oyin lọ”

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2300]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- búra pe àwọn ife imumi odo adágún rẹ ni ọjọ igbende pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ, Iyẹn maa hàn ni oru ti o ṣókùnkùn ti ko si òṣùpá nínú ẹ; torí pé oru ti o ba ni òṣùpá, àwọn ìràwọ̀ rẹ ki i hàn; torí pé imọlẹ òṣùpá maa bo wọ́n mọlẹ, ati òru ti ko si ẹsujo nibẹ; torí pé bibẹ ẹsujo maa kọdi rírí àwọn ìràwọ̀, Ati pe àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí ó bá mu omi inú rẹ ko nii gbẹ òùngbẹ láéláé, òùngbẹ ti o si maa gbẹ ẹ́ kẹ́yìn nìyẹn, Àti pé odo adágún rẹ, gọ́tà méjì lati inú alujanna n dà sínú rẹ, ìbú rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ; Bákan náà ni àwọn origun odo adágún naa ṣe ri, gígùn rẹ maa ṣe déédéé ohun ti n bẹ laarin Hammaan, ìlú kan ni ti o wa ni ìpínlẹ̀ Balkọọhu ni ilẹ Shaam, titi dé Aelah, ilu kan ni ti a mọ ti o wa ni etí Shaam, Omi adágún naa funfun ju wàrà lọ, itọwo rẹ dùn ju oyin lọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ifi odo adágún rinlẹ pe o n bẹ, ati awọn oríṣiríṣi idẹra ti o wa ninu ẹ.
  2. Titobi odo adágún naa ati gigun rẹ ati ìbú rẹ ati pipọ àwọn ife imumi rẹ.