+ -

عَنْ ‌عَدِيِّ بْنِ حَاتِمٍ عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«الْيَهُودُ مَغْضُوبٌ عَلَيْهِمْ، وَالنَّصَارَى ضُلَّالٌ».

[صحيح] - [رواه الترمذي] - [سنن الترمذي: 2954]
المزيــد ...

Lati ọdọ 'Adiyyu ọmọ Haatim, lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu".

[O ni alaafia] - [Tirmiziy ni o gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2954]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju awọn Juu ni ìjọ kan ti Ọlọhun binu si wọn, nitori pe wọn mọ ododo wọn ko si ṣiṣẹ pẹlu rẹ. Ati pe awọn Nasara ni ìjọ ẹni anu; nitori pe wọn ṣe iṣẹ laini imọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Idapọ laaarin imọ ati iṣẹ jẹ igbala kuro ni oju ọna awọn ti a binu si ati awọn ẹni anu.
  2. Ikilọ kuro ni oju ọna awọn Juu ati Nasara, ati didunnimọ oju ọna taara ti o ṣe pe oun ni Isilaamu.
  3. Olukuluku ninu awọn Juu ati Nasara ni ẹni anu ti a binu si, ṣùgbọ́n eyi ti o jẹ ẹsa ju ninu awọn iroyin awọn Juu ni ibinu, ti eyi ti o jẹ ẹsa ju ninu awọn iroyin awọn Nasara ni anu.