+ -

عَنْ ‌عَائِشَةَ رَضِيَ اللهُ عَنْهَا قَالَتْ:
تَلَا رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ هَذِهِ الْآيَةَ: {هُوَ الَّذِي أَنْزَلَ عَلَيْكَ الْكِتَابَ مِنْهُ آيَاتٌ مُحْكَمَاتٌ هُنَّ أُمُّ الْكِتَابِ وَأُخَرُ مُتَشَابِهَاتٌ فَأَمَّا الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ زَيْغٌ فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَابَهَ مِنْهُ ابْتِغَاءَ الْفِتْنَةِ وَابْتِغَاءَ تَأْوِيلِهِ، وَمَا يَعْلَمُ تَأْوِيلَهُ إِلَّا اللَّهُ، وَالرَّاسِخُونَ فِي الْعِلْمِ يَقُولُونَ آمَنَّا بِهِ كُلٌّ مِنْ عِنْدِ رَبِّنَا وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّا أُولُو الْأَلْبَابِ} [آل عمران: 7]. قَالَتْ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «فَإِذَا رَأَيْتِ الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ مَا تَشَابَهَ مِنْهُ فَأُولَئِكَ الَّذِينَ سَمَّى اللهُ، فَاحْذَرُوهُمْ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: "c2">“A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè} [Aal Imraan: 7]. O sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "c2">“Ti o ba ti ri awọn ti n tẹle ohun ti o ruju ninu ẹ, àwọn ti Ọlọhun sọ nìyẹn, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn”
.
O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ – àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: "c2">“A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè}. Inú rẹ ni Ọlọhun ti sọ pé Oun ni O sọ Kuraani kalẹ fun Anọbi Rẹ, eyi ti o ni àwọn aaya ti itumọ wọn ko ruju, ti a si mọ idajọ wọn, àwọn ni ipilẹ tira naa ati ibuṣẹrisi rẹ, àwọn naa ni ibuṣẹrisi nígbà tí a ba yapa, o tun n bẹ ninu rẹ àwọn aaya miiran ti a le fun ni itumọ oríṣiríṣi, ti itumọ wọn maa n daru lójú àwọn èèyàn kan, tàbí ki o maa lero pe atako n bẹ láàrin rẹ ati aaya mìíràn, lẹyin naa ni Ọlọhun wa ṣàlàyé bi àwọn èèyàn ṣe n lo pẹ̀lú àwọn aaya yii, àwọn ti igbunri kuro nibi òdodo n bẹ ninu ọkan wọn maa fi eyi ti ko ruju silẹ, wọn maa wa gba eyi ti o ruju mu, lati fi le da iruju silẹ ati lati le ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọn a si maa yi itumọ rẹ pada si ohun ti o maa ba ifẹ-inu wọn mu, ṣùgbọ́n àwọn ti ẹsẹ wọn rinlẹ ninu imọ maa mọ eyi ti o ruju yii, wọn maa wa da a pada sibi eyi ti ko ruju, wọn si maa gba a gbọ pe ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni o ti wa, kò si rọrùn ki o daru tabi tako ara wọn, ṣùgbọ́n Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè ti o ni alaafia. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fun iya àwọn mumini, Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ti o ba ti ri awọn ti n tẹle eyi ti o ruju, àwọn yẹn ni Ọlọhun sọ ninu ọ̀rọ̀ Rẹ pe: {Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn}, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn, ki ẹ si ma tẹti si wọn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. AL-MUHKAM ninu awọn aaya Kuraani ni: Ohun ti itumọ rẹ ko pamọ, AL-MUTASHAABIH ni: Ohun ti o ni ju itumọ kan lọ, ti o si bukaata si ìwòye ati agbọye.
  2. Ìkìlọ̀ kuro nibi dídarapọ̀ mọ́ àwọn ti n gbúnrí kuro nibi ododo, ati awọn oni adadaalẹ, ati awọn ti maa n da iruju silẹ lati ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ati lati ko iyèméjì ba wọn.
  3. O n bẹ nibi pipari aaya naa pẹ̀lú gbólóhùn Rẹ pe: { Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè} ìdọ́gbọ́nbú awọn ti wọn gbúnrí kuro nibi òdodo, ati ẹyìn fun awọn ti ẹsẹ wọn rinlẹ ninu imọ, o n túmọ̀ si pe: Ẹni ti ko ba ti lo ìrántí, ti o wa tẹle ifẹ-inu rẹ, onítọ̀hún ko si ninu awọn onilaakaye.
  4. Itẹle nnkan ti o ruju maa n fa igbunri ọkàn kuro nibi òdodo.
  5. Dandan ni ki a da àwọn aaya to ruju ti a le ma gbọ itumọ wọn yé pada si awọn aaya ti ko ruju.
  6. Ọlọhun ṣe apá kan ninu Kuraani ni nǹkan ti ko ruju, O si ṣe apá kan ni ohun ti o ruju; ki o maa jẹ àdánwò fun awọn èèyàn ki awọn onigbagbọ le yatọ si awọn ẹni anù.
  7. O n bẹ nibi wíwà nnkan ti o ruju nínú Kuraani: Àfihàn ọla àwọn onimimọ lori awọn to yatọ si wọn, ati mímú làákàyè mọ̀ nipa ikudiẹ-kaato rẹ; ki o le jupa-jusẹ silẹ fun Ẹni ti O da a, ki o si jẹwọ ikagara rẹ.
  8. Ọla ti n bẹ fun ki ẹsẹ o rinlẹ ninu imọ ati ìjẹ́dandan iduroṣinṣin nibẹ.
  9. Ọrọ meji ni àwọn to n ṣàlàyé itumọ Kuraani sọ nipa diduro nibi gbólóhùn {ALLOOHU} nibi ọ̀rọ̀ Rẹ ti O sọ pe {WA MAA YAH’LAMU TAHWIILAHUU ILLAA ALLOOHU WAR-RAASIKHUUNA FIL IL’M}, ẹni tí ó bá dúró lórí {ALLOOHU}, a jẹ́ wipe AT-TAHWIIL maa túmọ̀ si mímọ pàápàá nǹkan ati ohun ti ko si bi eeyan ṣe fẹ mọ̀ ọ́n bii ọ̀rọ̀ nipa ẹ̀mí, ati igba ti ayé maa parẹ́, ninu awọn nnkan ti o ṣe pe Ọlọhun nìkan ni O ni imọ nipa rẹ, àwọn ti ẹsẹ wọn rinlẹ ninu imọ maa gba a gbọ́, wọn si maa fa imọ nipa pàápàá rẹ le Ọlọhun lọ́wọ́, wọn si maa jupa-jusẹ silẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ko ba duro lórí gbólóhùn {ALLOOHU}, AT-TAHWIIL maa túmọ̀ si itumọ ati àlàyé, o maa wa jẹ pe Ọlọhun mọ̀ ọ́n, àwọn ti ẹsẹ wọn rinlẹ ninu imọ naa si mọ̀ ọ́n, wọn maa wa gba a gbọ́, wọn si maa da a pada sibi eyi ti ko ruju.