عَنْ قَتَادَةَ رحمه الله قال:
حَدَّثَنَا أَنَسُ بْنُ مَالِكٍ رَضِيَ اللهُ عَنْهُ أَنَّ رَجُلًا قَالَ: يَا نَبِيَّ اللهِ كَيْفَ يُحْشَرُ الْكَافِرُ عَلَى وَجْهِهِ؟ قَالَ: «أَلَيْسَ الَّذِي أَمْشَاهُ عَلَى الرِّجْلَيْنِ فِي الدُّنْيَا قَادِرًا عَلَى أَنْ يُمْشِيَهُ عَلَى وَجْهِهِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ؟» قَالَ قَتَادَةُ: بَلَى وَعِزَّةِ رَبِّنَا.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6523]
المزيــد ...
Lati ọdọ Qataadah- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe:
Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fún wa pe arákùnrin kan sọ pé: Irẹ Anọbi Ọlọhun, bawo ni wọn ṣe maa gbé keferi dìde lori ojú rẹ? O sọ pe: “Njẹ Ẹni tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?”, Qataadah sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi agbára Olúwa wa búra.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6523]
Wọn bi Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pe: Báwo ni wọn ṣe maa gbe Kèfèrí dìde lori ojú rẹ ni Ọjọ́ Àjíǹde?! Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Ǹjẹ́ Olọhun tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?! Ọlọhun ni ikapa lori gbogbo nǹkan.