+ -

عَنْ ‌عَائِشَةَ رضي الله عنها:
أَنَّ رَجُلًا قَعَدَ بَيْنَ يَدَيِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَقَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ، إِنَّ لِي مَمْلُوكِينَ يَكْذِبُونَنِي وَيَخُونُونَنِي وَيَعْصُونَنِي، وَأَشْتُمُهُمْ وَأَضْرِبُهُمْ، فَكَيْفَ أَنَا مِنْهُمْ؟ قَالَ: «يُحْسَبُ مَا خَانُوكَ وَعَصَوْكَ وَكَذَّبُوكَ وَعِقَابُكَ إِيَّاهُمْ، فَإِنْ كَانَ عِقَابُكَ إِيَّاهُمْ بِقَدْرِ ذُنُوبِهِمْ كَانَ كَفَافًا، لَا لَكَ وَلَا عَلَيْكَ، وَإِنْ كَانَ عِقَابُكَ إِيَّاهُمْ دُونَ ذُنُوبِهِمْ كَانَ فَضْلًا لَكَ، وَإِنْ كَانَ عِقَابُكَ إِيَّاهُمْ فَوْقَ ذُنُوبِهِمُ اقْتُصَّ لَهُمْ مِنْكَ الْفَضْلُ»، قَالَ: فَتَنَحَّى الرَّجُلُ فَجَعَلَ يَبْكِي وَيَهْتِفُ، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أَمَا تَقْرَأُ كِتَابَ اللهِ: {وَنَضَعُ الْمَوَازِينَ الْقِسْطَ لِيَوْمِ الْقِيَامَةِ فَلا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا}، الْآيَةَ»، فَقَالَ الرَّجُلُ: وَاللهِ يَا رَسُولَ اللهِ، مَا أَجِدُ لِي وَلهُمْ شَيْئًا خَيْرًا مِنْ مُفَارَقَتِهِمْ، أُشْهِدُكَ أَنَّهُمْ أَحْرَارٌ كُلُّهُمْ.

[ضعيف] - [رواه الترمذي]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- pé:
Arákùnrin kan jókòó níwájú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo ni àwọn ẹrú kan ti wọn maa n pa irọ́ fun mi, wọn tun maa n janba mi, wọn si tun maa n yapa àṣẹ mi, mo maa n bú wọn, mo si maa n lù wọ́n, báwo ni ọ̀rọ̀ mi ati wọn ṣe maa jẹ ni ọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "c2">“Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn, tí ìyà ti o fi jẹ wọn ba jẹ odiwọn ẹṣẹ wọn, a jẹ pe o ti ṣe déédéé ara wọn, o o nii ni ẹsan, o o si nii jẹ ìyà, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba kere si ẹṣẹ wọn, ìyẹn maa jẹ alekun fun ẹ, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba ju ẹṣẹ wọn lọ, wọn maa gba ẹ̀san alekun naa lara rẹ fun wọn”, o sọ pe: Ni arákùnrin naa wa rìn jìnnà, ni o ba bẹ̀rẹ̀ si nii sunkún ti o si n pariwo, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: "c2">“Ṣe o o ka tira Ọlọhun ti o sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan}, aaya”
, ni arákùnrin naa wa sọ pé: Mo fi Ọlọhun bura irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mi o ri ohun ti o loore fun emi ati awọn ju ki a pínyà lọ, mo n fi ọ jẹ́rìí pe gbogbo wọn ti di olómìnira.
O ni alaafia - Tirmiziy ni o gba a wa

Àlàyé

Arákùnrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati wa fi ẹjọ́ bi àwọn ẹrú rẹ ṣe n hùwà sùn, pe wọn maa n pa irọ́ fun un, wọn si maa n janba rẹ nibi agbafipamọ, wọn si maa n rẹ́ ẹ jẹ nibi ibalopọ, wọn si maa n yapa àṣẹ rẹ, oun naa si maa n bu wọn, o si maa n na wọn lati kọ́ wọn ni ẹ̀kọ́, o wa bi i leere nipa bi ọrọ oun ṣe maa jẹ pẹlu wọn ni Ọjọ́ Àjíǹde? Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn, tí ìyà ti o fi jẹ wọn ba jẹ odiwọn ẹṣẹ wọn, o o nii ni ẹsan, o o si nii jẹ ìyà, tí iya ti o fi jẹ wọn ba kere si ẹṣẹ wọn, o maa jẹ alekun ẹsan fun ẹ, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba ju ẹṣẹ wọn lọ, wọn maa fi iya jẹ ìwọ naa, wọn si maa gba odiwọn ti o ba le lọ́wọ́ rẹ, wọn si maa fun wọn, ni arákùnrin naa wa rìn jìnnà, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii n sunkún ti o si n pariwo, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Ṣé o o ka tira Ọlọhun ti o sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò} [Al-Anbiyaa: 47], wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹni kankan ni Ọjọ́ Àjíǹde, àwọn òṣùwọ̀n si maa wa laarin awọn èèyàn pẹ̀lú déédéé, ni arákùnrin naa wa sọ pé: Mo fi Ọlọhun bura irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mi o ri nǹkan kan ti o ni ọla fun èmi ati awọn ju ki a pínyà lọ, mo n fi ọ jẹ́rìí pe gbogbo wọn ti di ọmọlúwàbí nítorí tí Ọlọhun; ni ti ipaya ìṣirò ati ìyà.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ododo saabe naa nipa fífún àwọn ẹrú rẹ ni òmìnira ni ti ipaya ìyà Ọlọhun.
  2. Gbigba ẹ̀san lara alabosi, ti o ba ṣe deede odiwọn abosi naa, tabi ti o ba kere si i, nǹkan ti o ni ẹtọ ni, ṣùgbọ́n ki o ju u lọ, eewọ ni.
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori biba àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ àti àwọn ọ̀lẹ lò pọ̀ pẹlu dáadáa.