عَنِ البَرَاءِ بْنِ عَازِبٍ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«المُسْلِمُ إِذَا سُئِلَ فِي القَبْرِ: يَشْهَدُ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللَّهِ»، فَذَلِكَ قَوْلُهُ: {يُثَبِّتُ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا بِالقَوْلِ الثَّابِتِ فِي الحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الآخِرَةِ} [إبراهيم: 27].
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4699]
المزيــد ...
Lati ọdọ Al-Baraa ọmọ 'Azib- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Musulumi ti wọn ba bi i leere ninu saare: O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni", ìyẹn ni ọrọ rẹ pé: (Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (Ibrahim, Ayah 27).
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4699]
Wọn maa bi olugbagbọ leere ninu saare, awọn mọlaika meji ti a fi ṣe amojuto ìyẹn maa beere lọwọ rẹ nipa ìyẹn, awọn mejeeji ni Munkar ati Nakeer, gẹgẹ bi orúkọ awọn mejeeji ṣe wa ninu ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn hadiisi, O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe eleyii ni ọrọ ti o fi ẹsẹ rinlẹ ti Ọlọhun sọ nipa rẹ pé: (Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (Ibrahim, Ayah 27).