عَنِ ابْنِ عُمَرَ رضي الله عنهما أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«أُمِرْتُ أَنْ أُقَاتِلَ النَّاسَ حَتَّى يَشْهَدُوا أَنْ لاَ إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللَّهِ، وَيُقِيمُوا الصَّلاَةَ، وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ، فَإِذَا فَعَلُوا ذَلِكَ عَصَمُوا مِنِّي دِمَاءَهُمْ وَأَمْوَالَهُمْ إِلَّا بِحَقِّ الإِسْلاَمِ، وَحِسَابُهُمْ عَلَى اللَّهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 25]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka, ti wọn ba ṣe iyẹn, wọn ti daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn kuro lọdọ mi afi pẹlu ẹtọ Isilaamu, ati pe ìṣirò iṣẹ wọn wa lọwọ Ọlọhun".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 25]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun pa oun láṣẹ pẹlu biba awọn ọṣẹbọ ja titi wọn fi maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti a le jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati ki wọn jẹrii ìránṣẹ́ fun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati ṣiṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti ijẹrii yii n beere fun bii sisọ awọn irun maraarun-un ni ọsan ati alẹ, ati ki wọn maa yọ saka ti o jẹ ọran-anyan fun awọn ti wọn lẹtọọ si i. Ti wọn ba ti ṣe awọn alamọri yii, dajudaju Isilaamu maa daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn, ti pipa wọn ko nii lẹtọọ afi ti wọn ba wu iwa ọdanran kan ti wọn wa maa fi lẹtọọ si pipa lori rẹ tori okùnfà idajọ Isilaamu, lẹyin naa, ni ọjọ igbedide Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa ṣe amojuto ìṣirò iṣẹ wọn nigba ti O mọ awọn kọ̀kọ̀ wọn.