+ -

عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بْنِ مَسْعُودٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ:
حَدَّثَنَا رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ وَهُوَ الصَّادِقُ المَصْدُوقُ: «أَنَّ خَلْقَ أَحَدِكُمْ يُجْمَعُ فِي بَطْنِ أُمِّهِ أَرْبَعِينَ يَوْمًا وَأَرْبَعِينَ لَيْلَةً، ثُمَّ يَكُونُ عَلَقَةً مِثْلَهُ، ثُمَّ يَكُونُ مُضْغَةً مِثْلَهُ، ثُمَّ يُبْعَثُ إِلَيْهِ المَلَكُ، فَيُؤْذَنُ بِأَرْبَعِ كَلِمَاتٍ، فَيَكْتُبُ: رِزْقَهُ وَأَجَلَهُ وَعَمَلَهُ وَشَقِيٌّ أَمْ سَعِيدٌ، ثُمَّ يَنْفُخُ فِيهِ الرُّوحَ، فَإِنَّ أَحَدَكُمْ لَيَعْمَلُ بِعَمَلِ أَهْلِ الجَنَّةِ حَتَّى لاَ يَكُونُ بَيْنَهَا وَبَيْنَهُ إِلَّا ذِرَاعٌ، فَيَسْبِقُ عَلَيْهِ الكِتَابُ، فَيَعْمَلُ بِعَمَلِ أَهْلِ النَّارِ فَيَدْخُلُ النَّارَ، وَإِنَّ أَحَدَكُمْ لَيَعْمَلُ بِعَمَلِ أَهْلِ النَّارِ حَتَّى مَا يَكُونُ بَيْنَهَا وَبَيْنَهُ إِلَّا ذِرَاعٌ، فَيَسْبِقُ عَلَيْهِ الكِتَابُ، فَيَعْمَلُ عَمَلَ أَهْلِ الجَنَّةِ فَيَدْخُلُهَا».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 7454]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Mas’huud- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún si ni: “Wípé wọ́n maa kó ẹ̀dá ẹnikan nínú yín jọ sínú ikùn ìyá rẹ̀ fún ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà yóò di ẹjẹ dídì fun ogójì ọjọ́, lẹyin naa yoo di baaṣi ẹran fun ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà wọn maa ran malaika si i, wọ́n maa pa a láṣẹ pẹ̀lú gbólóhùn mẹrin kan, wọn maa waa kọ: Arisiki rẹ, ati àsìkò rẹ, ati iṣẹ rẹ, ati pe ṣe oloriburuku ni abi oloriire, lẹ́yìn naa wọn maa fẹ́ ẹ̀mí si i lára, dájúdájú ẹnikan ninu yin yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin alujanna ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ iná, yoo si wọ ọ, dájúdájú ẹnikan nínú yin, yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ ina, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin iná ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, yoo si wọ̀ ọ́”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 7454]

Àlàyé

Ibnu Mas’ud sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọ̀rọ̀, olódodo ni nibi ọ̀rọ̀ rẹ, ẹni tí wọ́n sọ òdodo fun ni; torí pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ òdodo fun un, O sọ pe: Dajudaju ẹnìkan nínú yin, wọn ko ẹ̀dá rẹ jọ, ìyẹn ni pe ti ọkùnrin ba sunmọ ìyàwó rẹ, wọn maa ko àtọ̀ rẹ ti o fọnka jọ ninu ikun obìnrin ti o maa wa ni àtọ̀ fun ogójì ọjọ́, Lẹ́yìn náà yoo di ẹ̀jẹ̀ dídì, oun naa ni ẹjẹ ti ó ki ti kò sàn, eyi ni ogójì ọjọ́ kejì, Lẹyin naa yoo di baaṣi ẹran, oun naa ni egige kan ninu ẹran ni odiwọn nǹkan ti a le rún lẹ́nu, èyí ni ogójì ọjọ́ kẹta, Lẹyin naa ni Ọlọhun maa ran malaika si i lati fẹ́ ẹ̀mí si i lára lẹyin ti ogójì ọjọ́ kẹta bá parí, Wọn maa pa malaika naa láṣẹ ki o kọ àwọn nǹkan mẹ́rin kan, àwọn naa ni: Arisiki rẹ, oun naa ni odiwọn ohun ti o maa rí ninu idẹra ni ayé rẹ, Ati asiko rẹ, òun naa ni igba ti o fi maa wa láyé, Ati iṣẹ rẹ, ki ni? Ati pe ṣe oloriburuku ni abi oloriire. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- búra pé ẹnikan yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, ti iṣẹ rẹ maa jẹ́ iṣẹ rere ni eyi ti o hàn si awọn èèyàn, yoo wà bẹ́ẹ̀ titi ti ohun ti o maa wa láàrin rẹ ati alujanna ko fi nii ju apá lọ, itumọ ni pe: Ohun ti o maa ku fun un lati de inu alujanna naa maa da gẹgẹ bii ẹni tí ohun ti o ṣẹku láàárín rẹ ati ààyè kan lórí ilẹ̀ ko ju déédéé apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ ati ohun ti wọn kadara fun un, ìgbà náà ni yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ ina, yoo si pari ayé rẹ lórí ẹ, yoo si wọ ina; Torí pé májẹ̀mú gbígba iṣẹ ni ki èèyàn má kúrò lórí rẹ, ki o si ma yi i padà, àwọn èèyàn míràn ma maa ṣiṣẹ́ ọmọ iná titi ti o fi maa sunmọ ki o wọ̀ ọ́, ti ohun ti o maa ṣẹku láàrin rẹ àti ina ko nii ju odiwọn apá ninu ilẹ̀ lọ, ni àkọsílẹ̀ ati kádàrá ba maa borí rẹ, yoo waa maa ṣiṣẹ́ ọmọ alujanna, yoo si wọ̀ ọ́.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìkángun àwọn àlámọ̀rí ni igbẹyin naa ni ohun ti o ba ti ṣiwaju ninu kadara.
  2. Ikilọ kúrò nibi gbígba ẹtan pẹ̀lú àwọn àwòrán iṣẹ; torí pé igbẹyin gan ni iṣẹ.