+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«نَارُكُمْ جُزْءٌ مِنْ سَبْعِينَ جُزْءًا مِنْ نَارِ جَهَنَّمَ»، قِيلَ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، إِنْ كَانَتْ لَكَافِيَةً. قَالَ: «فُضِّلَتْ عَلَيْهِنَّ بِتِسْعَةٍ وَسِتِّينَ جُزْءًا كُلُّهُنَّ مِثْلُ حَرِّهَا».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3265]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, iná ayé gan ti tó. O sọ pe: “Ina Jahannama ju ti aye lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, gbígbóná ọkọọkan ninu ẹ da gẹgẹ bii gbígbóná iná ayé”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3265]

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, sọ fun wa pe ina aye yii jẹ ọkan ninu aadọrin awọn ẹya ina Jahannama, Gbígbóná iná ọjọ́ ìkẹyìn lágbára ju gbígbóná iná ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ ṣe déédéé gbígbóná ina ayé. Wọ́n sọ pé: Ìwọ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, iná ayé yìí ti tó láti fi fi ìyà jẹ àwọn ti wọn ba wọ̀ ọ́, O sọ pé: Ina Jahannama ju ina ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ da gẹgẹ bii rẹ nibi gbígbóná gidi gan.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ikilọ kúrò nibi iná ki awọn èèyàn le jìnnà sí àwọn iṣẹ ti o maa mú èèyàn wọ̀ ọ́.
  2. Titobi ina Jahannama ati iya rẹ, ati gbígbóná gidi gan rẹ.