+ -

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الخُدْرِيِّ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«يُؤْتَى بِالْمَوْتِ كَهَيْئَةِ كَبْشٍ أَمْلَحَ، فَيُنَادِي مُنَادٍ: يَا أَهْلَ الجَنَّةِ، فَيَشْرَئِبُّونَ وَيَنْظُرُونَ، فَيَقُولُ: هَلْ تَعْرِفُونَ هَذَا؟ فَيَقُولُونَ: نَعَمْ، هَذَا المَوْتُ، وَكُلُّهُمْ قَدْ رَآهُ، ثُمَّ يُنَادِي: يَا أَهْلَ النَّارِ، فَيَشْرَئِبُّونَ وَيَنْظُرُونَ، فَيَقُولُ: وهَلْ تَعْرِفُونَ هَذَا؟ فَيَقُولُونَ: نَعَمْ، هَذَا المَوْتُ، وَكُلُّهُمْ قَدْ رَآهُ، فَيُذْبَحُ ثُمَّ يَقُولُ: يَا أَهْلَ الجَنَّةِ خُلُودٌ فَلاَ مَوْتَ، وَيَا أَهْلَ النَّارِ خُلُودٌ فَلاَ مَوْتَ، ثُمَّ قَرَأَ: {وَأَنْذِرْهُمْ يَوْمَ الحَسْرَةِ إِذْ قُضِيَ الأَمْرُ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ} [مريم: 39]، وَهَؤُلاَءِ فِي غَفْلَةٍ أَهْلُ الدُّنْيَا {وَهُمْ لاَ يُؤْمِنُونَ} [مريم: 39]».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"c2">“Wọn maa mu ikú wá ni ìrísí àgbò ti o ni dúdú ati funfun lára, olupepe kan maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, wọn maa garùn wọn si maa wò, yoo wa sọ pé: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, lẹyin naa o maa pe pe: Ẹyin ọmọ iná, wọ́n maa garùn wọ́n sì maa wò, o maa waa sọ pe: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, wọn maa du u, lẹyin naa o maa sọ pé: Ẹyin ọmọ alujanna, gbére, ko si ikú mọ, ẹyin ọmọ iná, gbére, ko si ikú mọ, lẹyin naa ni o ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná} [Maryam: 39], àwọn wọ̀nyí wa ninu igbagbera ni àwọn ará ayé, {wọn kò sì gbàgbọ́} [Maryam: 30].

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, ṣalaye pe wọn yoo mu iku wa ni ọjọ Ajinde, gẹgẹ bii irisi akọ agutan ti o ni funfun ati dudu ninu rẹ, Wọn maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna! Wọn maa garun, wọn maa gbe ori wọn sókè, wọ́n si maa wò, Ó maa sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ mọ èyí? Wọ́n maa sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, ikú nìyí, gbogbo wọn sì ti rí i, wọ́n sì mọ̀ ọ́n. Lẹ́yìn náà ni olupepe naa maa pe pe: Ẹyin ọmọ ina, wọn maa ga ọrùn wọn, wọn maa gbe ori wọn sókè, wọ́n sì máa wò, Ó maa sọ pé: “Ṣé ẹ mọ èyí? Wọ́n maa sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, ikú nìyí, gbogbo wọn sì ti rí i, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; Wọn maa du u, lẹyin naa ni olupepe naa maa sọ pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, ẹ maa wa nibẹ gbere, ko si ikú, ẹyin ọmọ ina, ẹ máa wà nibẹ gbere, ko si ikú. Ki ìyẹn le jẹ alekun idẹra àwọn mumini, ati ìjìyà fun awọn Kèfèrí. Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́}. Ni ọjọ igbedide, wọn maa ya àwọn ọmọ alujanna ati awọn ọmọ ina si ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn si maa wọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ ba kangun si ti yoo si ṣe gbere nibẹ, Alaburu maa ká abamọ; torí pé ko ṣe dáadáa, ati ẹni tí ó ṣe to kù díẹ̀ kaato; torí ko lékún nibi iṣẹ rere.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìkángun ọmọniyan ni ọjọ ikẹyin ni gbere nínú alujanna tabi iná.
  2. Iṣọnilara ti o lagbara nipa ibẹru ọjọ́ igbedide, àti pé ọjọ abamọ ni.
  3. Alaye ṣíṣe gbere ìdùnnú àwọn ọmọ alujanna, ati ṣíṣe gbere ibanujẹ àwọn ọmọ iná.