عَنْ عَبْدِ اللهِ بْنِ عَمْرِو بْنِ الْعَاصِ رضي الله عنهما قَالَ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«كَتَبَ اللهُ مَقَادِيرَ الْخَلَائِقِ قَبْلَ أَنْ يَخْلُقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِخَمْسِينَ أَلْفَ سَنَةٍ، قَالَ: وَعَرْشُهُ عَلَى الْمَاءِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2653]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
"Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, o sọ pe: Aga ọla Rẹ wa ni ori omi".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2653]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun kọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kadara awọn ẹda ni ifọsiwẹwẹ ninu isẹmi ati iku ati arisiki ati nnkan ti o yatọ si ìyẹn sinu Wàláà ti A n ṣọ ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, ti yoo maa ṣẹlẹ̀ ni ibamu si nnkan ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ti kadara, Gbogbo nnkan ti o n bẹ n bẹ pẹlu idajọ Ọlọhun ati kadara Rẹ, Nnkan ti o ba ṣẹlẹ̀ si ẹru wọn ti kọ ọ pe ko nii fo o ru, nnkan ti o ba fo o ru wọn ti kọ ọ pe ko nii ṣẹlẹ̀ si i ni.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Jijẹ dandan nini igbagbọ ninu idajọ ati kadara.
  2. Kadara ni: Imọ Ọlọhun nipa gbogbo nnkan ati kikọ wọn Rẹ ati fifẹ Rẹ ati dida Rẹ ti O da wọn.
  3. Nini igbagbọ pe awọn kadara jẹ nnkan ti wọn kọ ṣíwájú dida sanmọ ati ilẹ, ìgbàgbọ́ yii maa ṣeso iyọnu ati jijupa-jusẹ silẹ.
  4. Dajudaju aga ọla Ọba Ajọkẹ-aye wa lori omi ṣíwájú dida sanmọ ati ilẹ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (65)