+ -

عَنْ طَاوُسٍ أَنَّهُ قَالَ: أَدْرَكْتُ نَاسًا مِنْ أَصْحَابِ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، يَقُولُونَ كُلُّ شَيْءٍ بِقَدَرٍ، قَالَ: وَسَمِعْتُ عَبْدَ اللهِ بْنَ عُمَرَ رضي الله عنهما يَقُولُ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«كُلُّ شَيْءٍ بِقَدَرٍ، حَتَّى الْعَجْزِ وَالْكَيْسِ، أَوِ الْكَيْسِ وَالْعَجْزِ».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Toowus, o sọ pe: Mo ba àwọn èèyàn kan nínú àwọn saabe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wọn maa n sọ pe gbogbo nǹkan pẹ̀lú kadara ni, o sọ pe: Mo gbọ ti Abdullah ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- ti n sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"c2">“Gbogbo nnkan pẹlu kádàrá ni, titi dórí ikagara ati ijafafa, tàbí ijafafa ati ikagara”.

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe gbogbo nnkan pẹ̀lú kádàrá ni; Titi dórí ikagara, oun naa ni: Gbígbé ohun ti o jẹ dandan láti ṣe jù silẹ ati dídá ìgbà si i ati lilọ ọ lára tayọ asiko rẹ, ninu ọrọ ayé ati ti alukiyaamọ. Ati ijafafa, oun naa ni: Ijafafa ati ọgbọ́n nípa àwọn àlámọ̀rí ayé àti alukiyaamọ. Ati pe Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ti kádàrá ikagara ati ijafafa ati gbogbo nǹkan, nǹkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ ni ayé àyàfi ki o ti ṣaaju ninu imọ Ọlọhun ati fifẹ Rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àlàyé adisọkan àwọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- nibi kádàrá.
  2. Gbogbo nnkan n ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú kádàrá Ọlọhun ti o fi dórí ikagara ati ijafafa.
  3. Ifi ẹri òdodo múlẹ̀ ati iṣọra àwọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- nibi gbígbé ọ̀rọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).
  4. Igbagbọ ninu gbogbo kádàrá, oore rẹ ni ati aburú rẹ.