عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«يَقْبِضُ اللَّهُ الأَرْضَ، وَيَطْوِي السَّمَوَاتِ بِيَمِينِهِ، ثُمَّ يَقُولُ: أَنَا المَلِكُ، أَيْنَ مُلُوكُ الأَرْضِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4812]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe:
«Ọlọhun a gba ilẹ mu, yoo si tun ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lẹyin naa ni Yoo waa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) ori ilẹ̀ da?».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4812]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fúnni niroo nipa pe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga Yio gba ilẹ mu ni ijọ igbende ti yio si pa a pọ, ati pe yio ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ ti Yio si ka a lori ara wọn tii Yio si pa a rẹ, lẹyin naa ni Yio wa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) orilẹ da?!

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Irannileti pe ọlá Ọlọhun ni yio maa sẹku ati pe ọlá ẹni ti o yatọ si I nkan ti yio yẹ ni.
  2. Gbigbọnngbọn Ọlọhun ati titobi ikapa Rẹ ati agbára Rẹ ati pipe ọla Rẹ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (55)