عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لَا تَقُومُ السَّاعَةُ حَتَّى يَتَقَارَبَ الزَّمَانُ، فَتَكُونَ السَّنَةُ كَالشَّهْرِ، وَيَكُونَ الشَّهْرُ كَالْجُمُعَةِ، وَتَكُونَ الْجُمُعَةُ كَالْيَوْمِ، وَيَكُونَ الْيَوْمُ كَالسَّاعَةِ، وَتَكُونَ السَّاعَةُ كَاحْتِرَاقِ السَّعَفَةِ الْخُوصَةُ».
[صحيح] - [رواه أحمد] - [مسند أحمد: 10943]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Aye o nii parẹ titi ti igba o fi sunmọ ara wọn, ti ọdún o waa da bi oṣu, ti oṣu o da bii jimọ (ọsẹ), ti jimọ o da bii ọjọ, ti ọjọ o da bii wakati, ti wakati o waa da bii sísun ewe igi dabinu».
[O ni alaafia] - [Ahmad ni o gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 10943]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni niroo pe dajudaju ninu awọn ami opin aye ni sisunmọra igba, Ti ọdún si maa rekọja gẹgẹ bi oṣu ṣe n rekọja, Ati pe oṣu maa rekọja gẹgẹ bi ọsẹ ṣe n rekọja, Ati pe jimọ (ọsẹ) maa rekọja gẹgẹ bi ọjọ kan ṣe n rekọja, Ati pe ọjọ maa rekọja gẹgẹ bi wakati kan ṣe n rekọja, Ati pe wakati maa rekọja ni iyara ti o lagbara gẹgẹ bi wọn ṣe maa n jo ewé igi dabinu.