عَنْ حُذَيْفَةَ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لَا تَقُولُوا: مَا شَاءَ اللهُ وَشَاءَ فُلَانٌ، وَلَكِنْ قُولُوا: مَا شَاءَ اللهُ ثُمَّ شَاءَ فُلَانٌ».
[صحيح بمجموع طرقه] - [رواه أبو داود والنسائي في الكبرى وأحمد] - [السنن الكبرى للنسائي: 10755]
المزيــد ...
Lati ọdọ Huzaifah- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ".
[O ni alaafia pẹ̀lú akojọpọ àwọn ọ̀nà rẹ] - [Abu Daud ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ahmad] - [As-Sunanul Kubrọ ti An-Nasaaiy - 10755]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki Musulumi maa sọ nibi ọrọ rẹ pé: "Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ", Tabi ohun ti Ọlọhun ati lagbaja ba fẹ; Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe fifẹ Ọlọhun ati erongba rẹ jẹ nnkan ti a tu kalẹ ti ẹnikẹni ko si ba A kẹgbẹ nibẹ, Ati pe o n bẹ nibi lilo harafi waw nibi asopọ naa, imuninimọlara pe ẹnìkan n ba Ọlọhun kẹgbẹ ati ifidọgba láàrin ẹni yẹn ati Ọlọhun. Ṣugbọn yoo maa sọ pé: Ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ, Ki o fi fifẹ ẹru tẹle fifẹ Ọlọhun pẹlu sisọ pe: "Thummo" dipo "Wa", nitori pe "Thummo" n ṣe àǹfààní ki nǹkan wa lẹyin ati lilọra.