+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«الْمُؤْمِنُ الْقَوِيُّ، خَيْرٌ وَأَحَبُّ إِلَى اللهِ مِنَ الْمُؤْمِنِ الضَّعِيفِ، وَفِي كُلٍّ خَيْرٌ، احْرِصْ عَلَى مَا يَنْفَعُكَ، وَاسْتَعِنْ بِاللهِ وَلَا تَعْجَزْ، وَإِنْ أَصَابَكَ شَيْءٌ، فَلَا تَقُلْ لَوْ أَنِّي فَعَلْتُ كَانَ كَذَا وَكَذَا، وَلَكِنْ قُلْ قَدَرُ اللهِ وَمَا شَاءَ فَعَلَ، فَإِنَّ (لَوْ) تَفْتَحُ عَمَلَ الشَّيْطَانِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2664]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ, maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe ọ ni anfaani, ki o si tun wa iranlọwọ pẹlu Ọlọhun, má si kagara, ati pe ti nkankan ba ṣẹlẹ si ọ, o ko wa gbọdọ sọ pe kani mo ṣe báyìí nkan báyìí báyìí ni ko ba jẹ, ṣugbọn sọ pe kọdarullāh wa maa sha'a fa‘al "akọsilẹ Ọlọhun ni, nkan ti O si fẹ ni O ṣe", tori pe (lao) "kani" o maa ṣina iṣẹ satani»

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2664]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pe dajudaju Mumini, daadaa ni gbogbo ẹ, ṣugbọn Mumuni ti o ni agbara ninu igbagbọ rẹ ati ipinnu rẹ ati dukia rẹ ati eyiti o yatọ si i ninu awọn ọna agbara ni oore ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọn-un-gbọn si tun nífẹ̀ẹ́ si i ju Mumini ti o jẹ ọlẹ lọ. Lẹyin naa ni o sọ asọtẹlẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fun Mumini pẹlu ṣiṣe awọn igbiyanju nibi nkan ti yio ṣe e ni anfaani ninu awọn alamọri aye ati ọjọ ìkẹyìn, pẹlu fifara ti Ọlọhun ti O mọ ti ọla Rẹ si tun ga, ati wiwa iranlọwọ pẹlu Rẹ, ati gbigbe ara le E. Lẹyin naa o tun kọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kuro nibi ikagara ati ojuriro ati imaa ṣe ọlẹ nibi ṣiṣe nkan ti o maa ṣe anfaani ni aye ati ọrun. Ti Mumuni ba gbiyanju nibi iṣẹ, ti o si tun ṣe awọn okunfa, lẹni ti o n wa ikunlọwọ Ọlọhun, ti o si tun wa oore lati ọdọ Ọlọhun, ko wa sí nkankan fun un lẹyin rẹ ayaafi ki o fa gbogbo alamọri rẹ le Ọlọhun lọwọ, ki o si tun lọ mọ pe dajudaju èyí tí Ọlọhun ba sẹsa ni oore. Nitori naa ti adanwo ba ṣẹlẹ si i lẹyin ìyẹn, ko gbọdọ sọ pe: Ka ni mo ṣe bayii, nkan bayii bayii ni ko ba jẹ"; Ati pe dajudaju gbolohun (kani) maa n ṣina iṣẹ satani" nibi titako kadara, ati kika abamọ lori nkan ti o ti bọ, ṣugbọn o maa sọ lẹni ti o jupa jusẹ silẹ ti o si tun yọnu pe: "Kọddarọ Allāhu, wa maa Sha'a fa‘ala“, Ati pe nkan ti o ṣẹlẹ yẹn wa ni ibamu si nkan ti Ọlọhun gba lero, ati pe Aṣeyiowu-U ni In, ko si si ẹni ti o le da akọsilẹ rẹ pada, ati pe ko si ẹni ti o le dá idajọ rẹ pada.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titayọ ara wọn awọn eeyan nibi igbagbọ.
  2. Nini ìfẹ́ si agbara nibi awọn iṣẹ; torí pé dajudaju yio maa ṣẹlẹ pẹlu rẹ anfaani ti ko le ṣẹlẹ pẹlu ikọlẹ.
  3. Ọmọniyan gbọdọ maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe e ni anfaani, ki o si fi nkan ti ko nii ṣe e ni anfaani silẹ.
  4. O jẹ dandan fun Mumuni ki o wa ikunlọwọ Ọlọhun nibi gbogbo alamọri rẹ, ki o si ma gbarale ara rẹ.
  5. Fifi akọsilẹ ati kadara rinlẹ, ati pe dajudaju ko tako ṣiṣe awọn okunfa ati gbigbiyanju nibi wiwa awọn nkan daadaa.
  6. Kikọ kuro nibi sisọ gbolohun «kani» ní ti ibinu nigba ti adanwo ba sọkalẹ, ati ṣiṣe ni eewọ titako idajọ ati akọsilẹ ti Ọlọhun.