عن النعمان بن بَشِير رضي الله عنه قال: سمعت النبيَّ صلى الله عليه وسلم يقول:
«الدُّعَاءُ هُوَ الْعِبَادَةُ»، ثُمَّ قَرَأَ: «{وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ} [غافر: 60]».
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه وأحمد] - [سنن الترمذي: 3247]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Adua naa ni ìjọsìn”, lẹyin naa ni o wa ka: “{Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ} [Gaafir: 60]”.
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 3247]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé adua naa ni ìjọsìn, ohun ti o jẹ dandan naa ni ki gbogbo ẹ jẹ ti Ọlọhun nìkan, yálà o jẹ adua ibeere ati wiwa nǹkan ni, bii ki o tọrọ lọ́dọ̀ Ọlọhun ohun ti o maa ṣe e ni anfaani, ati titi ohun ti o maa ko inira ba a ni ayé ati ọ̀run lọ, tabi o jẹ adua ìjọsìn, oun ni gbogbo nnkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ti o si yọnu si ninu awọn ọ̀rọ̀ ati awọn iṣẹ ti o han ati eyi ti o pamọ, àwọn ìjọsìn ti ọkàn tabi ara tabi dúkìá.
Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa mu ẹri wa lori ìyẹn, nibi ti o ti sọ pe: Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ}