عَنْ أَنَسٍ رضي الله عنه قَالَ:
كَانَ أَكْثَرُ دُعَاءِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «اللَّهُمَّ رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً، وَفِي الآخِرَةِ حَسَنَةً، وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6389]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6389]
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n ṣe adua lọpọlọpọ pẹ̀lú àwọn adua ṣókí tí o ko nǹkan ti o pọ sinu, ninu rẹ ni: «Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná» Ó ko oore ayé sínú, bíi ìpèsè arisiki ti o rọrun ti o gbooro, ti o jẹ alaali, ati ìyàwó ti o daa, ati ọmọ itutu ojú, ati ìsinmi, ati ìmọ̀ tí ó wúlò, ati iṣẹ́ rere, àti ohun tí ó jọ ìyẹn ninu awọn ohun ti èèyàn n fẹ ati ohun ti wọn ṣe ni ẹtọ, ati daadaa alukiyaamọ bii lila nibi awọn iya sàréè, ati ibuduro ni ọjọ igbende, ati iná, ati riri iyọnu Ọlọhun, ati nini idẹra gbere, ati isunmọ Oluwa Ajọkẹ-aye.