+ -

عَنْ شَدَّادِ بْنِ أَوْسٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«سَيِّدُ الِاسْتِغْفَارِ أَنْ تَقُولَ: اللَّهُمَّ أَنْتَ رَبِّي لاَ إِلَهَ إِلَّا أَنْتَ، خَلَقْتَنِي وَأَنَا عَبْدُكَ، وَأَنَا عَلَى عَهْدِكَ وَوَعْدِكَ مَا اسْتَطَعْتُ، أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ مَا صَنَعْتُ، أَبُوءُ لَكَ بِنِعْمَتِكَ عَلَيَّ، وَأَبُوءُ لَكَ بِذَنْبِي فَاغْفِرْ لِي، فَإِنَّهُ لاَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلَّا أَنْتَ» قَالَ: «وَمَنْ قَالَهَا مِنَ النَّهَارِ مُوقِنًا بِهَا، فَمَاتَ مِنْ يَوْمِهِ قَبْلَ أَنْ يُمْسِيَ، فَهُوَ مِنْ أَهْلِ الجَنَّةِ، وَمَنْ قَالَهَا مِنَ اللَّيْلِ وَهُوَ مُوقِنٌ بِهَا، فَمَاتَ قَبْلَ أَنْ يُصْبِحَ، فَهُوَ مِنْ أَهْلِ الجَنَّةِ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6306]
المزيــد ...

Lati ọdọ Shaddad bin Aws, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –:
“Olori iwaforijin ni ki o sọ pe: Allahummọ anta Rọbbii laa ilaaha illaa anta, khalaqtanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wawahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sanahtu, abuuhu laka binihmatika alayya, wa abuuhu bizambii, fagfir lii, fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta", o sọ pe: Ẹni ti o ba sọ ọ ni aarọ ti o si ni amọdaju pẹlu ẹ, ti o wa kú, ni ọjọ naa ki o to di irọlẹ, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna, ẹni tí ó bá sọ ọ ni alẹ ti o si ni amọdaju pẹ̀lú ẹ, ti o wa kú ki ilẹ o to mọ́, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna".

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6306]

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe: Awọn gbolohun kan wa fun wíwá idarijin, ati pe eyi ti o dara ju ti o si tobi ju ninu wọn ni ki ẹru maa sọ pe: "Allahummọ anta Robbii laa ilaaha illaa anta, khalaktanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wa wahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sonahtu, abuuhu laka binihmatika alayya wa abuuhu bizambii fagfir lii fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta" Ẹru maa fi taohid rinlẹ fun Ọlọhun ni akọkọ, ati pe Ọlọhun ni O da a, Oun si ni yoo maa jọ́sìn fun ti ko si orogun fun Un, ati pe oun wa lori ohun ti o ṣe adehun rẹ fun Ọlọhun bii ini igbagbọ si I ati itẹle E ni ibamu si ikapa rẹ; torí pé ko si bi ẹrú ṣe le sin Ọlọhun tó, ko le ni ikapa lati ṣe gbogbo nnkan ti Ọlọhun pa a láṣẹ ki o ṣe, bẹ́ẹ̀ si ni ko lee kapa lati dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ bi o ṣe yẹ, o si maa sadi Ọlọhun, o si tun maa dirọ mọ ọn, torí pé Oun ni Ẹni tí a maa n sadi kuro nibi aburu ti ẹrú ba ṣe, Ó maa fi rinlẹ ó sì maa jẹ́wọ́ ìbùkún rẹ̀ fún un, ó sì maa padà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípa fifirinlẹ àti jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìgbọràn rẹ̀, Lẹ́yìn ẹ̀bẹ̀ ipada si ọdọ Ọlọ́run yìí, ó maa bẹ Olúwa rẹ̀ pé kí O forijìn òun nípa bíbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, kí O sì dáàbò bò òun kuro nibi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú àforíjìn, oore àti àánú Rẹ̀, nítorí pé kò sẹ́ni tó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn, àfi Òun, Ọba ti O lágbára ti O gbọnngbọn. Lẹyin naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe o wa ninu awọn asikiri àárọ̀ ati alẹ, ẹni tí ó bá sọ ọ pẹ̀lú amọdaju ati ìrántí àwọn ìtumọ̀ rẹ̀, ati ini igbagbọ si i ni aarọ ọjọ́ naa, laarin yiyọ oorun si yiyẹ àtàrí rẹ, oun naa ni àsìkò ọsan, ti o wa ku, o maa wọ alujanna, Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ ní alẹ́, láti ìwọ̀ oòrùn títí di àfẹ̀mọ́jú, tí ó sì kú kí ilẹ o to mọ́, yóò wọ alujanna.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Awọn agbekalẹ fun wiwa àforíjìn yatọ si ara wọn, wọ́n si tun lọla jura wọn lọ.
  2. O yẹ ki ẹru o maa ṣe ojúkòkòrò lati maa gbadura si Ọlọhun pẹlu adua yii; nítorí pé oun ni olori iwaforijin.