عن أبي هريرة رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«كَلِمَتَانِ خَفِيفَتَانِ عَلَى اللِّسَانِ، ثَقِيلَتَانِ فِي الْمِيزَانِ، حَبِيبَتَانِ إِلَى الرَّحْمَنِ: سُبْحَانَ اللهِ الْعَظِيمِ، سُبْحَانَ اللهِ وَبِحَمْدِهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6406]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe:
“Gbólóhùn meji kan ti wọn fúyẹ́ lori ahọ́n, ti wọn wúwo ninu òṣùwọ̀n, ti Ajọkẹ-aye nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì ni: SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6406]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa gbólóhùn méjì kan ti ọmọniyan maa n pe ni gbogbo iṣesi láìsí inira nibẹ, ẹ̀san méjèèjì si tobi ninu òṣùwọ̀n, ati pe Oluwa wa Ajọkẹ-aye ti ọla Rẹ ga si nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì:
SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII; fun nǹkan ti méjèèjì ko sinu bii iroyin Ọlọhun pẹlu titobi ati pípé, ati fifọ Ọ mọ kuro nibi àléébù.