+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«لَيْسَ شَيْءٌ أَكْرَمَ عَلَى اللهِ تَعَالَى مِنَ الدُّعَاءِ».

[حسن] - [رواه الترمذي وابن ماجه وأحمد] - [سنن الترمذي: 3370]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe:
“Ko si nǹkan kan ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ju adua lọ”

[O daa] - [Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 3370]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ko si nnkan kan ninu awọn ijọsin ti o ni ọlá ni ọdọ Ọlọhun ju adua lọ; torí pé ó n bẹ ninu ẹ jijẹwọ ọ̀rọ̀ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ati jijẹwọ ikagara ẹrú ati ìní bukaata rẹ si I.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla adua, ati pe ẹni ti o ba pe Ọlọhun ni o n gbe E tobi, ti o si n fi rinlẹ fun Un pe Ọlọ́rọ̀ ni, mimọ ni fun Un, èèyàn kii pe tálákà, Olùgbọ́ si ni, èèyàn kii pe odi, Ọlọ́rẹ ni, eeyan kii pe ahun, Aláàánú ni, èèyàn kii pe ẹni ti o le, Ọba ti O ni ikapa ni, èèyàn kii pe ẹni ti o kagara, Ọba ti O sunmọ ni, ẹni tí ó jìnnà ko lee gbọ, ati ohun ti o yatọ si ìyẹn ninu awọn ìròyìn títóbi ati ẹwà fun Ọlọhun, mimọ ni fun Un, Ọba ti ọla Rẹ ga.