عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لَا يَسْتُرُ عَبْدٌ عَبْدًا فِي الدُّنْيَا إِلَّا سَتَرَهُ اللهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2590]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
"ẹru kan ko ni se ibasiri fún ẹrú kan láyé nbi ayaafi ki Ọlọhun se ibasiri fún un ni ọjọ igbende".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2590]
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) n salaye fun wa pé musulumi kan ko ni bo asiri ọmọ Iya rẹ tó jẹ musulumi nipa àlámọ̀rí kan ninu awọn àlámọ̀rí, ayaafi ki Ọlọhun bo asiri rẹ ni ọjọ igbende, iran iṣẹ ti a ba se náà ni a o gba ẹsan rẹ, yóò wa jasipe bibo àṣírí Ọlọhun fún un ni pé yóò bo asiri awọn laifi rẹ àti àwọn ẹsẹ rẹ lati máa ṣe itanka rẹ lọdọ awọn ti wọn wani ibi gbangba Al-kiyaoma, o si le je pe bibo asiri rẹ ni ki Ọlọhun má ṣe iṣiro rẹ tabi ki o má ti ẹ mẹnu kaan rárá.