عَنْ جَابِرٍ رضي الله عنه قَالَ: سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَبْلَ وَفَاتِهِ بِثَلَاثٍ يَقُولُ:
«لَا يَمُوتَنَّ أَحَدُكُمْ إِلَّا وَهُوَ يُحْسِنُ بِاللهِ الظَّنَّ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2877]
المزيــد ...
Lati ọdọ Jaabir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: mo gbọ tí Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ ni ọdun mẹta síwaju koto fi ayé silẹ báyi pé:
"Ẹnikan ninu yin ko gbọ ku ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2877]
Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) gba musulumi níyànjú lati má kùú ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun pẹlu ki o fi abala inireti sọdọ Ọlọhun leke nígbàtí nba pọka iku lọwọ n'ireti pe Ọlọhun Yóò ṣekẹ rẹ yóò ṣe amojukuro fún un; nitoripe ifoya ni nkan ti wọn beere fún ki a le ri iṣẹ se daada, ìṣesí un kii se iṣesí iṣẹ ṣiṣe, nkan ti wọn fẹ nibẹ ni ki ireti borí.