عن عبد الله بن عمرو رضي الله عنهما عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«لَيْسَ الْوَاصِلُ بِالْمُكَافِئِ، وَلَكِنِ الْوَاصِلُ الَّذِي إِذَا قُطِعَتْ رَحِمُهُ وَصَلَهَا».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 5991]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o gba a wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - ó sọ pé:
"Kii ṣe ẹniti n fi dáadáa ṣẹ̀san dáadáa ni ó pé perepere nibi siso okùn-ẹbi, ṣugbọn oluso okùn-ẹbi gangan ni ẹniti ó jẹ́ pé nigba ti awọn eniyan bá já okùn-ẹbi rẹ̀ dànù, ó maa n so o padà".
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5991]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé dajudaju eniyan tó pé nibi siso okun-ẹbi ati ṣiṣe daadaa si awọn ibatan rẹ̀ kii ṣe eniyan tí ó ń san daadaa pẹlu daadaa nikan, bi ko ṣe pé ẹniti ó ń so okun-ẹbi gangan, tó sì pé nibi siso okun-ẹbi ni ẹnití o jẹ́ pé bí wọ́n bá já okun-ẹbi rẹ̀, ó maa so o padà, kódà bí wọ́n bá ṣe aburú si i; dáadáa ni oun maa ṣe sí wọn padà.