عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه:
أَنَّ رَجُلًا قَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ إِنَّ لِي قَرَابَةً أَصِلُهُمْ وَيَقْطَعُونِي، وَأُحْسِنُ إِلَيْهِمْ وَيُسِيئُونَ إِلَيَّ، وَأَحْلُمُ عَنْهُمْ وَيَجْهَلُونَ عَلَيَّ، فَقَالَ: «لَئِنْ كُنْتَ كَمَا قُلْتَ، فَكَأَنَّمَا تُسِفُّهُمُ الْمَلَّ وَلَا يَزَالُ مَعَكَ مِنَ اللهِ ظَهِيرٌ عَلَيْهِمْ مَا دُمْتَ عَلَى ذَلِكَ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2558]
المزيــد ...
Láti ọdọ Abu Hurayrah kí Ọlọhun yọnu si:
Dájúdájú arakunrin kan sọ pé: irẹ ojisẹ Ọlọhun mo ni awọn ẹni tí mo nso okun ẹbi wọn pọ ti awọn si nja kuro lọdọ mi, mo nṣe daada si wọn bẹẹ ni wọn se àìda si mi, mo nṣe suuru pẹlu wọn bẹẹ ni wọn wù iwa aimọkan pẹlu mi, Anọbi sọ pé: "tó bá ṣe pé bí o se wà lo sọ yii, bi ẹni pe ìwà wọn ti su ọ bayii, ikun lọwọ Ọlọhun konii ye konii gbo fun ọ lori wọn lópin igbati o ba ti wà bẹẹ".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2558]
Arákùnrin kan lọ fẹjọ sùn Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) pe oun ni ẹbi ati ibipọ ti oun nba wọn ṣe pọ pẹlu daada bẹẹ ni awọn nba lo pẹlu àìda; oun aa máa so wọn pọ bẹẹ ni awọn nja kúrò ní ara oun, oun aa máa se daada sí wọn pẹlu rere ati ise ojúṣe bẹẹ awọn aa maa se àìda sí oun pẹlu abosi àti ìwà omugọ, òun aa máa ni suuru pẹlu wọn aa sì maa se amojukuro fun wọn, bẹẹ ni wọn a maa wu iwa aimọkan sí oun pẹlu ọrọ ẹnu ati iṣẹ ti koda, nje ki oun tún tẹsiwaju lati máa so okun ẹbi pọ pẹlu nkan ti oun sọ yii?
ni Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) wa sọ fún un pa: ti o ba se pé bí ọrọ seri ni o sọ yi dájúdájú o ti ko iyẹpẹrẹ bá wọn, o si ti jẹ kí wọn rí ra wọn ni ẹni abuku, bi ẹni pé o nfun wọn ni eérú gbóná jẹ ni; nítorí daada rẹ tó pọ tí o nṣe fún wọn àti aburú ti wọn nṣe fun ara wọn, iranlọwọ láti ọdọ Ọlọhun wa ti yóò máa kún ọ lọwọ lórí wọn konii yẹ konii gbo pẹlu rẹ, ti yóò si máa daabo bo ọ níbi suta (aburu) wọn lópin ìgbà tí o bá wà lórí ise daada rẹ sí wọn tí awọn náà wà lórí ise àìda sí ọ.