+ -

عَنْ زَيْدِ بْنِ خَالِدٍ الجُهَنِيِّ رضي الله عنه أَنَّهُ قَالَ:
صَلَّى لَنَا رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ صَلَاةَ الصُّبْحِ بِالْحُدَيْبِيَةِ عَلَى إِثْرِ سَمَاءٍ كَانَتْ مِنَ اللَّيْلَةِ، فَلَمَّا انْصَرَفَ أَقْبَلَ عَلَى النَّاسِ، فَقَالَ: «هَلْ تَدْرُونَ مَاذَا قَالَ رَبُّكُمْ؟» قَالُوا: اللهُ وَرَسُولُهُ أَعْلَمُ، قَالَ: «أَصْبَحَ مِنْ عِبَادِي مُؤْمِنٌ بِي وَكَافِرٌ، فَأَمَّا مَنْ قَالَ: مُطِرْنَا بِفَضْلِ اللهِ وَرَحْمَتِهِ، فَذَلِكَ مُؤْمِنٌ بِي وَكَافِرٌ بِالْكَوْكَبِ، وَأَمَّا مَنْ قَالَ: بِنَوْءِ كَذَا وَكَذَا، فَذَلِكَ كَافِرٌ بِي وَمُؤْمِنٌ بِالْكَوْكَبِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 846]
المزيــد ...

Lati ọdọ Zaid bn Khalid Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa fun wa ni Hudaibiyah lẹ́yìn ojo ti o rọ̀ ni òru, lẹ́yìn tí ó kírun tán, o kọju si awọn eniyan, o sọ pe: “Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ, ẹni tí ó bá sọ pé: Wọ́n rọ òjò fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ, ìyẹn ni ẹni tí ó gbagbọ ninu Mi ti o si ṣe aigbagbọ si ìràwọ̀, ṣugbọn ẹni tí o ba sọ pe: Pẹ̀lú ìràwọ̀ bayii bayii, ìyẹn ni ẹni tí o ṣe aigbagbọ ninu Mi, ti o wa ni igbagbọ ninu ìràwọ̀”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 846]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa ni Hudaibiya- oun ni oko kan ti o sunmọ Mẹka- lẹyin ti ojo rọ ni alẹ yẹn, Igba ti o salamọ ti o ki irun rẹ tan o doju kọ awọn eniyan, o si bi wọn pe: Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ? Wọn da a lohun pe: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, O sọ pe: Dajudaju Ọlọhun ṣàlàyé pe awọn eniyan pin si meji nigba ti ojo ba rọ: Ipin kan ti o ni igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati ipin ti o jẹ alaigbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Ṣugbọn ẹni ti o sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, ti o fi rirọ ojo ti sọ́dọ̀ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; ìyẹn ni olugbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Aṣẹ̀dá Aṣeyiowuu ninu aye, o si jẹ alaigbagbọ si irawọ. Ṣugbọn ẹni ti o ba sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu irawọ bayii bayii; ìyẹn ni alaigbagbọ ninu Ọlọhun, olugbagbọ ninu irawọ, o si jẹ aigbagbọ kekere nigba ti o ṣe afiti rirọ ojo si ara irawọ; ati pe Ọlọhun ko ṣe e ni okunfa ti sharia tabi ti kadara, Ṣugbọn ẹni ti o ba ṣe afiti rirọ ojo ati nnkan ti o yàtọ̀ si i ninu awọn ìṣẹ̀lẹ̀ ori ilẹ̀ si ara lilọ-bibọ àwọn ìràwọ̀ nibi yíyọ wọn ati jijabọ wọn, ti o n ni adisọkan pe oun ni ẹni ti o n ṣe e gangan, o ti jẹ alaigbagbọ ni aigbagbọ ti o tobi.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Fifẹ sisọ gbolohun lẹyin rírọ ojo pé: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ.
  2. Ẹni ti o ba ṣe afiti rírọ ojo ati nnkan ti o yàtọ̀ si i si ara irawọ ni ti dida ati mimu-nnkan-bẹ, o ti di alaigbagbọ ni ti aigbagbọ ti o tobi, ṣugbọn ti o ba ṣe afiti rẹ lori pe okunfa ni, o ti di alaigbagbọ ni ti aigbagbọ kekere; nitori pe ko ki n ṣe okunfa ti sharia tabi ti imọlara.
  3. Dajudaju idẹra maa n jẹ okunfa fun aigbagbọ ti wọn ṣe aimore si i, o si maa n jẹ okunfa igbagbọ ti wọn ba dupẹ rẹ.
  4. Kíkọ sisọ gbolohun: “Wọn rọ ojo fun wa pẹlu irawọ bayii bayii, ko da ki wọn gbero asiko pẹ̀lú rẹ, láti dènà àtẹ̀gùn lọ síbi ẹbọ.
  5. Jijẹ dandan siso ọkan papọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi fifa awọn idẹra wá, ati titi awọn iya kuro.