عن طارق بن أشيم الأشجعي رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ قَالَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَكَفَرَ بِمَا يُعْبَدُ مِنْ دُونِ اللهِ حَرُمَ مَالُهُ وَدَمُهُ، وَحِسَابُهُ عَلَى اللهِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 23]
المزيــد ...
Lati ọdọ Tooriq ọmọ Ashyam Al-Ash-ja'iy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 23]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba sọ ti o si jẹrii pẹlu ahọn rẹ pe “LAA ILAAHA ILLALLOHU”, o n túmọ̀ si pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ti o bọpa-bọsẹ kuro nibi gbogbo awọn ẹsin yatọ si Isilaamu, dajudaju dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ jẹ eewọ fun awọn Musulumi, ohun ti ó kàn wa ni eyi ti o han ninu iṣẹ rẹ, wọn ko nii gba dukia rẹ, wọn ko si nii ta ẹjẹ rẹ silẹ, afi ti o ba da ẹṣẹ kan tabi wuwa ọdanran kan ti o maa sọ ìyẹn di dandan ni ìbámu si awọn idajọ Isilaamu.
Ati pe Ọlọhun ni yoo ṣe ìṣirò rẹ ni ọjọ igbedide, ti o ba jẹ olododo yoo san an lẹsan, ti o ba jẹ sọbẹ-selu yoo fi iya jẹ ẹ.