عَنْ عُقْبَةَ بْنِ عَامِرٍ الْجُهَنِيِّ رضي الله عنه:
أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَقْبَلَ إِلَيْهِ رَهْطٌ، فَبَايَعَ تِسْعَةً وَأَمْسَكَ عَنْ وَاحِدٍ، فَقَالُوا: يَا رَسُولَ اللهِ، بَايَعْتَ تِسْعَةً وَتَرَكْتَ هَذَا؟ قَالَ: «إِنَّ عَلَيْهِ تَمِيمَةً»، فَأَدْخَلَ يَدَهُ فَقَطَعَهَا، فَبَايَعَهُ، وَقَالَ: «مَنْ عَلَّقَ تَمِيمَةً فَقَدْ أَشْرَكَ».
[حسن] - [رواه أحمد] - [مسند أحمد: 17422]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Uqbah ọmọ ‘Aamir Al-Juhaniy - ki Ọlọhun yọnu si i:
Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ikọ kan wa ba a, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn ti o ka ọwọ duro fun ẹnikan, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan o si fi eleyii silẹ? O sọ pe: «Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ», ni o (arakunrin yẹn) wa ti ọwọ rẹ wolẹ ti o si fa a ja, nigba naa ni o (Anabi) wa gba ọwọ adehun (ibura) rẹ, ni o wa sọ pe: «Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)».
[O daa] - [Ahmad ni o gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 17422]
Awọn ikọ kan wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ti onka wọn sì jẹ mẹwaa, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn lori Isilaamu ati itẹle aṣẹ, ti ko si gba ọwọ adehun (ibura) ti ẹni kẹwàá, nigba ti wọn wa beere nipa idi ìyẹn o sọ - ki ikẹ ati ọla maa ba a - pe: Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ, oun naa ni nkan ti wọn maa n de tabi ti wọn maa n sokọ latara ilẹkẹ ati nkan miran yatọ si i lati fi ti ojukoju tabi inira danu. Ni arakunrin naa wa ti ọwọ rẹ bọ aaye ti agbekọ naa wa ti o si ja a ti o si bọra kuro nibẹ, nigba naa ni o gba ọwọ adehun pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o (Anabi) wa sọ lẹni ti n kilọ kuro nibi agbekọ ti o si n ṣe alaye idajọ rẹ pe: Ẹni ti o ba so agbekọ ó ti ṣe ẹbọ (mu orogun mọ Ọlọhun)”