عَنْ ابْنِ عَبَّاسٍ رضي الله عنهما قَالَ:
قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ غَدَاةَ الْعَقَبَةِ وَهُوَ عَلَى نَاقَتِهِ: «الْقُطْ لِي حَصًى» فَلَقَطْتُ لَهُ سَبْعَ حَصَيَاتٍ، هُنَّ حَصَى الْخَذْفِ، فَجَعَلَ يَنْفُضُهُنَّ فِي كَفِّهِ وَيَقُولُ: «أَمْثَالَ هَؤُلَاءِ فَارْمُوا» ثُمَّ قَالَ: «أَيُّهَا النَّاسُ، إِيَّاكُمْ وَالْغُلُوَّ فِي الدِّينِ، فَإِنَّما أَهْلَكَ مَنْ كَانَ قَبْلَكُمْ الْغُلُوُّ فِي الدِّينِ».
[صحيح] - [رواه ابن ماجه والنسائي وأحمد] - [سنن ابن ماجه: 3029]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni àárọ̀ jiju okuta ipari, ti o si wa lori rakunmi rẹ pé: "Ba mi mu okuta kekere kan" mo wa mu awọn okuta kekere meje fun un, awọn ni okuta kéékèèké tí a maa n fi ìka méjì jù, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii ju wọn si atẹlẹwọ rẹ, o si n sọ pe: "Awọn iru awọn wọnyi ni ẹ maa ju" lẹyin naa o sọ pe: "Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin".
[O ni alaafia] - [Ibnu Maajah ati Nasaa'iy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Ibnu Maajah - 3029]
Ọmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n sọ pe oun wa pẹlu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ iduran ni àárọ̀ jiju okuta jamratul ákọ́bà ni hajj idagbere, Bayii ni o ba pa a láṣẹ ki o ba a sa okuta ti o maa jù, o si ba a sa òkúta meje, ikan nibẹ da gẹgẹ bii èso himmas tabi èso bunduk, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe wọn si ọwọ rẹ lẹyin naa o mì wọn, o wa sọ pe: Irú wọn ní ìwọ̀n ni ki ẹ jù, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ nipa aṣẹju ati imu nnkan le koko ati kikọja aala nibi awọn alamọri ẹsin, ati pe kikọja aala ko iparun ba awọn ijọ ìṣáájú ati aṣeju ati imu nnkan le koko nibi ẹsin.