+ -

عَنْ عَبْدِ اللهِ بْنِ مَسعودٍ رضي الله عنه عن رَسولِ اللهِ صلى الله عليه وسلم قال:
«الطِّيَرَةُ شِرْكٌ، الطِّيَرَةُ شِرْكٌ، الطِّيَرَةُ شِرْكٌ، -ثلاثًا-»، وَمَا مِنَّا إِلَّا، وَلَكِنَّ اللهَ عَزَّ وَجَلَّ يُذْهِبُهُ بِالتَّوَكُّلِ.

[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه وأحمد]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun.

O ni alaafia - Ibnu Maajah ni o gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ikilọ kuro nibi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, oun ni fifuramọ aburu latara eyikeyii nnkan kan ti a le gbọ́ lo jẹ ni tabi ti a le ri, ninu awọn ẹyẹ tabi awọn ẹranko tabi awọn oni aisan tabi awọn onka tabi awọn ọjọ tabi eyi ti o yàtọ̀ si wọn, Ṣugbọn o dárúkọ awọn ẹyẹ nitori pe o gbajumo nigba aimọkan, ati pe ipilẹ rẹ ni títú awọn ẹyẹ silẹ nigba ti wọn ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii irin-ajo tabi okowo tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, ti o ba fo si apa ọtun, yoo ni ifuramọ daadaa yoo si maa ba nnkan ti o fẹ ṣe lọ, ti o ba fo si apa osi, yoo ni ifuramọ aburu yoo si da ọwọ duro kuro nibi nnkan ti o fẹ ṣe. O sọ pe dajudaju ẹbọ ni, ifuramọ aburu ẹbọ ni; nitori pe ko si ẹni ti o le mu daadaa wa afi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu danu afi Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.
Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe nnkan kan ninu ifuramọ aburu le waye ninu ọkan Musulumi, ṣùgbọ́n o jẹ dandan fun un lati fi igbarale Ọlọ́hun ti i danu, pẹlu ṣíṣe awọn okunfa.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni; nitori pe isopọ ọkan pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun n bẹ nibẹ.
  2. Pataki pipaara awọn ibeere ti wọn ṣe koko, ki wọn le ha wọn ki o si lee rinlẹ ninu awọn ọkan.
  3. Igbarale ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa n mu fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore lọ.
  4. Pipaṣẹ igbarale Ọlọhun nikan ṣoṣo ati siso ọkan pọ mọ Ọn- mimọ ni fun Un-.