+ -

عَنْ ‌وَرَّادٍ كَاتِبِ الْمُغِيرَةِ بْنِ شُعْبَةَ قَالَ: أَمْلَى عَلَيَّ الْمُغِيرَةُ بْنُ شُعْبَةَ فِي كِتَابٍ إِلَى مُعَاوِيَةَ:
أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ يَقُولُ فِي دُبُرِ كُلِّ صَلَاةٍ مَكْتُوبَةٍ: «لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ، وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، اللَّهُمَّ لَا مَانِعَ لِمَا أَعْطَيْتَ، وَلَا مُعْطِيَ لِمَا مَنَعْتَ، وَلَا يَنْفَعُ ذَا الْجَدِّ مِنْكَ الْجَدُّ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 844]
المزيــد ...

Lati ọdọ Warrood olukọwe Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah, o sọ pe: Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah pe àpèkọ fun mi ninu iwe kan si Mu’aawiyah pe:
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘atoita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 844]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘ah'toita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”.
O n túmọ̀ si pe: Mo n fi rinlẹ mo si n gba gbolohun imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo “Laa ilaaha illallohu” wọlé, ati pe ijọsin ododo mo n fi i rinlẹ fun Ọlọhun, mo si n kọ ọ fun ẹni ti o yatọ si i, ati pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, mo si n fi ọla gangan ti o pe rinlẹ fun Ọlọhun, ati gbogbo ọpẹ awọn ara inu sanmọ ati ilẹ jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nigba ti O ṣe pe Onikapa ni lori gbogbo nnkan, ati pe nnkan ti Ọlọhun ba kadara rẹ ninu fifun ati kikọ, ko si oludapada kankan fun un, lọdọ Rẹ, ọrọ ko lee ṣe ọlọrọ ni anfaani, bi ko ṣe pe iṣẹ rere ni yoo ṣe e ni anfaani.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe iranti yii ni nnkan ti a fẹ lẹyin awọn irun fun nnkan ti o ko sinu ninu awọn gbolohun imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo ati ọpẹ.
  2. Yiyara si ṣíṣe àwọn sunnah, ati fifọn wọn ka.